Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Eeyan mẹta la gbọ pe o ku, nigba tawọn mi-in fara pa ninu ijamba ọkọ to waye loju ọna marosẹ Ilọrin si Jẹbba-Bode-Saadu, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe ọkọ tirela kan to ni nọmba T0431KT ati ọkọ ero alawọ pupa Toyota Corolla pẹlu nọmba AFN 274 NY, ni wọn kọ lu ara wọn loju ọna marosẹ Ilọrin si Jẹbba-Bode-Saadu, ni nnkan bii aago mẹfa aabọ aṣaalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, latari ere asapajude.
Ọga ajọ ẹsọ oju popo nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Jonathan Owoade, sọ pe eeyan meje lo fara kaasa nibi iṣẹlẹ naa, mẹta ku loju-ẹsẹ, ti mẹrin si fara pa yanna yanna. Owoade tẹsiwaju pe ọkunrin kan, obinrin meji, ni wọn pade iku ojiji, ti wọn si sare ko awọn to ṣeṣe lọ sile-iwosan olukọni Fasiti Ilọrin (UITH), ti wọn si ko awọn oku lọ si mọsuari ọsibitu yii kan naa. O waa rọ awọn awakọ pe ki wọn yee sare asapajude loju popo, tori pe ẹmi ko laarọ.