Eeyan mẹta ku sinu ṣọọṣi Kerubu l’Ọṣun, ọlọpaa ti mu pasitọ atiyawo ẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ iwadii lori iku ojiji to pa eeyan mẹta sinu ṣọọṣi kerubu kan lagbegbe Ọfatẹdo, nipinlẹ Ọṣun.
ALAROYE gbọ pe pasitọ ijọ naa, Taiwo Ọlaniyi, ẹni ọdun mejielogoji ni oun ati iyawo rẹ, Kẹmi Ọlaniyi, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, tun n ṣiṣẹ iwosan (healing home) nibẹ.
Ọṣẹ iwẹ la gbọ pe pasitọ fun awọn oloogbe mẹtẹẹta ọhun; Rasheedat Mufutau, ẹni ọdun mejidinlọgọta, Anifowoṣe Baṣira, ẹni ọdun mejidinlaaadọta ati Abdul-Rahman Afọlabi to jẹ ọmọ oṣu mẹsan-an, ko si pẹ ti wọn fi ọṣẹ naa wẹ ti wọn gbẹmi-in mi.
Iṣẹlẹ to ṣẹlẹ lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ọhun la gbọ pe o da ipayinkeke silẹ laduugbo naa, awọn olokuu si ti fẹẹ gbe oku wọn ko too di pe awọn agbofinro da si ọrọ ọhun.
A gbọ pe igbe ẹkun Abudul-Rahman to jẹ ọmọ oṣu mẹsan an-loru ọjọ naa lo ji awọn araadugbo, ko si pẹ ti iya rẹ gbe e jade janna-janna latinu ṣọọṣi lọmọ naa jade laye.
Ọrọ yii di ariwo, nigba ti awọn eeyan si bẹrẹ si i tu inu ṣọọṣi ni wọn ri oku Rasheedat ati Bashirat ni nnkan bii aago mẹfa idaji ku ogun iṣẹju, ti wọn si lọọ fi ọrọ naa to ọlọpaa leti.
Ko pẹ rara ti awọn ọlọpaa fi de si ṣọọṣi naa to wa lẹyin Ọlọfa Grammar School, Ọfatẹdo, ti wọn si mu tọkọ-tiyawo naa. Awọn mejeeji si ti n ran ọlọpaa lọwọ ninu iwadii wọn.

Leave a Reply