Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Eeyan bii mẹta ni wọn pade iku ojiji lasiko ija nla kan to waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ ati Aye niluu Igbọkọda, lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
ALAROYE gbọ pe lara awọn to ba iṣẹlẹ ọhun rin ọkunrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Niboto Number 1, to jẹ olori ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ atawọn ọmọ abẹ rẹ meji, Adekunle ati Ogunsipẹ.
Ija ajakuata yii ni wọn lo waye lagbegbe College Road, Igbọkọda, nijọba ibilẹ Ilajẹ, ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ naa.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn afurasi bii mẹfa lọwọ ọlọpaa ti tẹ lori iṣẹlẹ ọhun, ti wọn si ti foju wọn ba ile-ẹjọ Majisreeti to wa lagbegbe Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ ta a wa yii, lati waa jẹjọ ẹsun bii marun-un ti wọn fi kan wọn.
Awọn afurasi to n jẹjọ lọwọ ọhun ni Ẹhinmẹtan Adeọla pẹlu Ẹniọla Ibrahim ti wọn jẹ ọmọ ogun ọdun, Samson Ọjatula ati Samson Ugbosanmi, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, Sunday Kalẹjaye, ẹni ọdun mẹrinlelogun ati Titilọla Onbọwadun to jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun.
Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn n’ile-ẹjọ ni ipaniyan, ṣiṣe ẹgbẹ okunkun, ṣiṣe amulo nnkan ija oloro ati kiko ara jọ lọna tí ko bofin mu.
Awọn ẹsun ọhun ni Agbefọba, Augustine Omhinemehen, ni o ta ko abala ofin mẹfa ati ikeje ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2005, eyi to lodi si ẹgbẹ okunkun ṣiṣe, ipaniyan ati lilo nnkan ija oloro lọna ti ko bofin mu.
O rọ adajọ lati fọwọ si fífi awọn olujẹjọ naa pamọ sọgba ẹwọn titi tile-ẹjọ yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.
Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ R. O. Yakubu gba ẹbẹ agbefọba wọle pẹlu bo ṣe ni ki wọn lọọ fi awọn olujẹjọ mẹfẹẹfa pamọ sọgba ẹwọn titi di ogunjọ, oṣu Kejila, ọdun ta a wa yii.