Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ko din leeyan mẹtadinlogun to jona ku laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Keji, ọdun 2022 yii, nigba ti bọọsi akero kan ati tanka fori sọra wọn lori biriiji Iṣara, loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan.
Nnkan bii aago marun-un idaji nijamba yii ṣẹlẹ gẹgẹ bi Ọga FRSC Ogun, Ahmed Umar, ṣe ṣalaye.
O ni awọn ko ti i le sọ iye eeyan ti ijamba naa kan, ṣugbọn awọn ti wọn dagbere faye nipa jijona ku ko din ni mẹtadinlogun.
Nigba to n ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ, Umar sọ pe aitẹle ofin irinna lo fa ijamba ọkọ naa.
O loun ko le sọ ẹni to jẹbi ninu awọn mejeeji, ṣugbọn Eko ni ọkọ akero ti n bọ, nigba ti tanka n bọ lati Ibadan.
Umar fi kun alaye naa pe wiwa ọkọ niwakuwa lo da wahala yii silẹ. O loun lo fa a ti bọọsi to ni nọmba ZT 28 KLD, fi lọọ lari mọ tanka ti wọn kọ ‘Dangote Flour’ si lara naa. To fi di pe ina sọ, tawọn eeyan si bẹrẹ si i jona.
O waa fi kun un pe ijamba to ṣee dena lo ṣe bẹẹ paayan mẹtadinlogun yii, to si jẹ pe ka lawọn ọlọkọ yii ṣe ohun to yẹ ni, ko sohun ti yoo fa ijamba yii rara.
Ninu gbogbo awọn to jona ku yii, ọkunrin kan, obinrin kan, ati ọmọbinrin kekere kan nikan lo lawọn da mọ, ti wọn ko jona di eeru, o lawọn yooku jona kọja idanimọ ni.
Umar ba ẹbi awọn to ṣalaisi yii kẹdun, o si ni ki wọn kan si ileeṣẹ FRSC Ogere lati gbọ ẹkunrẹrẹ nipa iṣẹlẹ aburu naa.