Florence Babaṣọla
Lasiko ti a n koroyin yii jọ, o ti di eeyan mọkanla to ku ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ niluu Gbọngan, lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, nigba ti eeyan mejilelogun fara pa yannayanna.
Bọọsi akero meji la gbọ pe wọn fori sọ ara wọn ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ, eeyan mẹtalelọgbọn lo si wa ninu awọn mọto naa.
Agbẹnusọ fun ajọ ẹṣọ ojuupopo l’Ọṣun, Agnes Ogungbemi, ṣalaye pe ere asapajude ti mọto bọọsi mejeeji n sa lo ṣokunfa ijamba nla naa.
Ogungbemi ṣalaye pe lojiji ni mọto Mazda E2000 alawọ funfun to ni nọmba KJA 392 Ay ati Toyota Hiace alawọ dudu to ni nọmba GWL 427 YM fori sọ ara wọn niwaju sẹkiteriati ijọba ibilẹ Ayedaade.
O ṣalaye pe ọkunrin mọkanla lo ku loju-ẹsẹ, nigba ti obinrin meji ati ọkunrin mọkandinlogun fara pa pupọ.
O fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti gbe mẹrindinlogun lara awọn to fara pa lọ sileewosan Ariremakọ, niluu Gbọngan, nigba ti wọn ko awọn mẹfa lọ sileewosan Central Hospital, niluu Osogbo.
Mẹwaa lara awọn to gbẹmi-in mi ninu ijamba naa ni wọn ti ko lọ sile igbokuu-pamọsi ti ileewosan Ọbafẹmi Awolọwọ University Teaching Hospital, Ile-Ife.
A gbọ pe Hausa ni ẹni kan to ṣẹku, awọn mọlẹbi ti wọn wa nipinlẹ Eko si ti gba oku rẹ lọ fun sinsin.