Efe Ajagba gba ife-ẹyẹ kẹrinla lagbo ẹṣẹ kikan

Oluyinka Soyemi

Ọmọ ilẹ wa to n ṣe bẹbẹ lagbo ẹṣẹ kikan lagbaaye, Efe Ajagba, ti gba ami-ẹyẹ kẹrinla bayii lẹyin to na Jonnie Rice ilẹ Amẹrika lalẹ ana ni gbọngan The Bubble, to wa ni Vegas, nilẹ Amẹrika.

Lẹyin ipele kẹwaa ija naa lawọn adajọ mẹtẹẹta, iyẹn Max DeLucaAdalaide Byrd ati Dave Moretti, sọ pe Efe lo jawe olubori.

Eyi nigba keji tawọn adajọ yoo fimọ ṣọkan lati fun ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn naa lami-ẹyẹ, igba akọkọ ni ija to ba Ali Eren Demirezen ja loṣu keje, ọdun to kọja.

Ṣugbọn ki i ṣe pe ija naa rọrun fun Efe rara, Jonnie naa fi gbogbo agbara ja, nnkan ko kan ṣẹnuure fun un ni.

Oriire tuntun yii ni ija kẹrinla fun Efe, gbogbo ẹ lo si ti yege, bẹẹ lo fi ẹṣẹ gbe awọn alatako ẹ ṣubu nigba mọkanla.

Leave a Reply