Jọkẹ Amọri
Ẹgbẹ agba Yoruba nni, Afẹnifẹre, ti ṣabẹwo ibanikẹdun siluu Ọwọ, nipinlẹ Ondo, nibi ti wọn ti ki awọn eeyan ilu naa, Gomina Akeredolu, awọn ọmọ ijọ St Francis Catholic Church, ti iṣẹlẹ naa ti waye atawọn ti wọn fara pa ninu iṣẹlẹ naa, ti wọn si gbadura pe ki Ọlọrun dawọ aburu bẹẹ duro.
Lasiko abẹwo naa ni wọn yọju si Gomina Akeredolu to gba wọn lalejo, bakan naa ni wọn fi ẹbun owo ta ijọ ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ atawọn tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si lọrẹ.
Lara awọn to ṣabẹwo ibanikẹdun yii ni Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Baba Ayọ Adebanjọ, Igbakeji wọn, Ọba Ọladipọ Ọlaitan, Oloye Olu Falae, Gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹ, Oluṣẹgun Mimiko, Gomina Ogun tẹlẹ, Ọtunba Gbenga Daniel, Ọga ọlọpa to ti fẹyinti, Tunji Alapinni atawọn mi-in bẹẹ.