Monisọla Saka
Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹta, oṣu Kejila, ọdun yii, ni ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC), ipinlẹ Eko, ṣide ipolongo ibo fun gomina to wa nipo, Ọgbẹni Babajide Sanwo-Olu ati Igbakeji ẹ, Ọbafẹmi Hamzat, fun ibo gomina ọdun 2023. Awọn igbimọ eleto ipolongo ibo ẹgbẹ nipinlẹ naa ni wọn ṣeto ipolongo ibo to gun rege, to si da bii pe wọn n ṣọdun ni ọhun, eyi to waye ni papa iṣere Mobọlaji Johnson Stadium, Onikan, nipinlẹ Eko.
Gbogbo awọn oludije dupo aṣofin ni ẹkun mẹtẹẹta, atawọn ipo aṣoju-ṣofin lẹgbẹ oṣelu APC, awọn olubadamọran sijọba to wa nipo, awọn oloye ati ọmọ ẹgbẹ kaakiri ijọba ibilẹ ogun ati ijọba ibilẹ Idagbasoke, awọn aṣaaju ẹsin, awọn aṣoju iran Hausa-Fulani nipinlẹ Eko (Arewa Community), awọn aṣoju awọn ẹya mi-in loriiṣiriṣii, ẹgbẹ awọn oniṣowo atawọn oṣere tiata ilẹ wa ni wọn peju pesẹ sibẹ.
Lasiko to n ki awọn eeyan kaabọ nibi eto naa, adari awọn ikọ olupolongo ibo nipinlẹ Eko, Sẹnetọ Ganiu Solomon, rọ awọn eeyan lati jọwọ, fibo wọn gbe Gomina Babajide Sanwo-Olu, Igbakeji ẹ, Ọbafẹmi Hamzat, atawọn oludije mi-in ninu ẹgbẹ oṣelu APC wọle.
O ni, “Anfaani ati iyi nla ni fun mi lati waa ṣide ipolongo ibo gomina ti yoo waye lọdun 2023 lonii yii.
Ma a fẹ ki gbogbo wa tẹti silẹ gẹgẹ bi gomina wa to wa lori aleefa ṣe fẹẹ fun wa niroyin awọn iṣẹ ribiribi ti wọn ti gbe ṣe lati bii ọdun mẹta ataabọ ti wọn ti wa nipo. Nitori idi eyi la ṣe n bẹbẹ fun ibo yin, kẹ ẹ ba wa fi gbe gbogbo awọn to n dupo kan tabi omi-in ninu ẹgbẹ wa wọle, ki iṣẹ rere ti wọn dawọ le le tẹsiwaju”.
Ninu ọrọ tiẹ, Gomina Babajide Sanwo-Olu, dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Eko fun ẹmi-ìṣe, ifẹ ati atilẹyin wọn fawọn oludije dupo lẹgbẹ awọn ati APC ni pataki.
“Lọsẹ to kọja yii ni ẹgbẹ wa ṣide ipolongo ibo aarẹ, nibi tawọn araalu ti tu jade, ti wọn si tẹwọ gba Sẹnetọ Bọla Tinubu ati ẹni ti yoo ṣe igbakeji ẹ, Kashim Shettima. Ọsẹ kan lẹyin ẹ ree, mo tun dupẹ pe ẹ tun ṣe bẹẹ jade lati ṣatilẹyin fawọn eeyan wa to n dupo. Mo mọ ifẹ ati aduroti yin loore, ẹ ṣeun tẹ ẹ jade lati waa fi han pe ẹgbẹ kan ṣoṣo to wa nipinlẹ Eko ko ju APC naa lọ. A o ni i ṣalaimoore, bẹẹ la o ni i ja yin kulẹ.
“Bakan naa ni mo tun ki gbogbo awọn alatilẹyin ẹgbẹ APC fun bi wọn ṣe duro ti wa, irinajo ọdun mẹta ati aabọ yii dun, bẹẹ lo kun fun ipenija fun emi atawọn ti wọn n ba mi ṣejọba pọ. Oju wa ti ri oriṣiiriṣii, bii eto ọrọ aje ti ko lọ deede, ṣugbọn ti Ọlọrun n ba wa ṣe e.
‘‘Gẹgẹ ba a ṣe maa n sọ, to si jẹ ọrọ akọmọna ipolongo wa, ipinlẹ Eko n goke agba si i, nitori oniruuru aṣeyọri ta a ṣe labẹ eto ta a ti la kalẹ pe a fẹẹ ṣiṣẹ le lori ninu ijọba wa. Nitori idi eyi, ni mo ṣe n sọ pe, fun ipinlẹ Eko lati tubọ ga, ko si tẹsiwaju ju bayii lọ, ẹ jade sita, ẹ maa lọ lati ojule si ojule lati polongo, kẹ ẹ si dibo fawọn oludije dupo lẹgbẹ wa lati ipo aarẹ, titi kan gomina atawọn aṣofin”.
Pasitọ Cornelius Ọjẹlabi, ti i ṣe alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ naa sọ pe, kaadi idibo alalopẹ awọn eeyan ni ohun ẹnu wọn, ati agbara wọn lati gbe Sanwo-Olu wọle lẹlẹẹkeji.