Ọlajide Kazeem
Ni nnkan bii ọjọ meloo kan sẹyin lọkunrin oloṣelu kan, Ọnarebu Abdul Lateef Abdul Hakeem, binu kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC, o lawọn kan ti wọn jẹ agba ninu ẹgbẹ n ṣatako oriire oun.
Ẹgbẹ kan lo da silẹ, Iyẹpẹ 2023 lo pe e, ohun to si sọ pe o duro fun ni lilo ẹgbẹ naa lati fi ko araalu jọ fun oṣelu ati ṣíṣe itaniji fun wọn lori ọrọ oṣelu. Yatọ si eyi, ohun tí ẹgbẹ naa tun duro fun ni lati ṣíṣẹ fun un lori boun naa ṣe fẹẹ dupo gomina lọdun 2023 l’Ekoo.
Bi Abdul Hakeem ṣe da ẹgbẹ tuntun yii silẹ lawon agbaagba kan ti tako o ninu APC, ìyẹn naa lo sì mu un fi ẹgbẹ silẹ.
Ni bayii, awọn agbaagba kan ti pe e, wọn ti ni ko pada sinu ẹgbẹ. Ohun tí wọn sọ ni pe oloṣelu kan to ni ero rẹpẹtẹ lẹyin ni, bẹẹ lo maa jẹ adanu nla fun APC tiru Ọnarebu Yẹpẹ gẹgẹ bi awọn eeyan ẹ ṣe maa n pe e ba fi awọn silẹ.
Lara awọn to pe e sipade alaafia ni alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Alhaji Tunde Balogun, Ọmọọba Tajudeen Olusi, Abiodun Ogunlẹyẹ Rabiu Oluwa, Alhaji Bushira Alebioṣu ati Omooba Murphy Adetoro. Ohun tí wọn sọ fun un ní pe ko jọwọ, pada sinu ẹgbẹ, nítorí ipa nla lo n ko, ohun tó si gbe lọwọ, nnkan to tun le mu ẹgbẹ ni ero rẹpẹtẹ si i ni. Fun idi eyi, awọn ko ba a ja, ọrọ ẹgbẹ naa lo n ṣe.
Bakan naa ni wọn ti ṣeleri lati kun un lọwọ lori Iyẹpẹ 2023 to ṣagbekalẹ ẹ yii.
Bẹẹ gẹgẹ ni wọn ti parí wahala to wa laarin oun atawọn agba ẹgbẹ ti ko fara mọ akojọpọ to da silẹ naa.
AbdulLateef naa ti sọrọ, o ni loootọ loun tí pada sinu ẹgbẹ.
Kọmiṣanna fun ọrọ abẹle ni ọkunrin oloṣelu yii laye ijọba Ambọde, bakan naa lo tun jẹ oludamọran fun abẹnugan ile-igbimọ aṣofin, Mudashiru Ọbasa, ko too kuro ninu ẹgbẹ. Oun paapaa ti jẹ aṣofin nipinlẹ Eko ri, agbẹjọro ni, to si tun jẹ Alfaa to nimọ kuraani daadaa pẹlu.