Monisọla Saka
Ẹgbẹ All Progressive Congress (APC), ti fẹnu ko lati pade ni ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lati jiroro lori igba ati akoko ti ibo abẹle ẹgbẹ naa yoo waye ṣaaju ibo gbogbogboo ọdun 2023.
Ọgbẹni Felix Morka to jẹ Akọwe ẹgbẹ naa lo sọrọ yii di mimọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ pari yii.
O ni ipade ọhun yoo waye ni Congress Hall of Transcorp, Hilton Hotel, niluu Abuja. O fi kun un pe awọn yoo ṣagbeyẹwo awọn ti ẹgbẹ yoo fa kalẹ fun ibo gbogbogboo ọdun 2023 ati awọn ọrọ pataki miiran ninu ẹgbẹ wọn.
Ni ibamu pẹlu iwe ofin ikarundinlọgbọn, ẹsẹ ikeji ẹgbẹ APC, igbimọ amuṣẹṣe apapọ, National Working Committee (NWC), ti pe ipade apapọ ti yoo ṣakoso eto idibo ẹgbẹ APC, eyi ti yoo waye ni Ọjọruu, Wẹsidee, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 ti a wa yii.