Faith Adebọla, Eko
Asiko yii ti kọja awada ṣiṣe fun Baba Ijẹṣa, boya si l’Ọgbẹni Ọlanrewaju James le dẹrin-in pa ara rẹ lọwọ yii pẹlu bi ọpọ awọn ololufẹ rẹ ṣe kọyin si i lori ẹsun ifipa bọmọde lo pọ ti wọn fi kan an, bakan naa si ni ẹgbẹ awọn oṣere tiata ilẹ wa, TAMPAN, ti lawọn o ni i ṣatilẹyin kan fun afurasi ọdaran yii, bo ba jẹ loootọ lo huwa ọhun, ko lọọ maa da iya rẹ jẹ loju paali ni.
Ẹgbẹ TAMPAN (Theatre Arts and Motion Pictures Practitioners Association of Nigeria) sọ iduro wọn lori iṣẹlẹ yii lọjọ Abamẹta, Satide, ninu atẹjade kan ti ọga to wa lẹka iwadii ati akọsilẹ ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Yẹmi Amodu, fi lede. O ni ẹgbẹ awọn o ni i ṣatilẹyin fun ọmọ ẹgbẹ to yọ kẹlẹ huwa ainitiju ati iwa ọdaran eyikeyii, wọn lawọn o laṣọ aṣiri tawọn fẹẹ da bo iru ẹni bẹẹ, kaka bẹẹ, awọn ṣetan lati ṣatilẹyin fun ijọba ipinlẹ Eko ninu igbesẹ rẹ lati fidi idajọ ododo mulẹ lori ọrọ yii.
Atẹjade naa to tẹ ALAROYE lọwọ, ka lapa kan pe:
“A ri i gẹgẹ bii ojuṣe wa lati kede pe awa o fara mọ ẹsun ti wọn fi kan ọmọ ẹgbẹ wa yii, a si bẹnu atẹ lu iwa ailojuti ati iṣekuṣe ti wọn ni Ọgbẹni Olanrewaju James, ti inagijẹ rẹ n jẹ Baba Ijẹṣa jẹwọ pe oun hu. O ka ẹgbẹ wa, TAMPAN, lara, o si dun wa gan-an pe ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ wa ni wọn fi iru ẹsun iwa abani-loju-jẹ bayii kan, a da iwa ibajẹ buruku yii lẹbi gidi.
“Nitori ọrọ to gbẹgẹ gan-an lọrọ yii, ti ọrọ ọhun ṣi wa labẹ iwadii, a o ni i sọ ohunkohun lati ṣegbe tabi ta ko ẹni tọrọ yii kan, ju pe ka fi ero wa han lodi si iwakiwa ọhun lọ.
“Gẹgẹ bii ẹgbẹ kan, a loye pe apẹẹrẹ to daa lawọn eeyan n reti latọdọ wa lawujọ, tori naa, a o ni i kẹrẹ lati ṣatilẹyin fun ijọba ki idajọ ododo le fidi mulẹ lori ọrọ yii.
“A ba awọn obi ati mọlẹbi ọmọde tọrọ yii kan kẹdun, a si rọ gbogbo awọn obi lati tubọ wa lojufo si ojuṣe wọn lati maa daabo bo awọn majeṣin wọn lọwọ ewu ati iwa ibajẹ to gbode kan lasiko yii.”