Ẹgbẹ awọn olukọ yunifasiti fopin si iyansẹlodi oṣu mẹjọ

Jọkẹ Amọri

Ẹgbẹ awọn olukọ nilẹ wa, ASUU, ti kede pe awọn ti fopin si iyanṣẹlodi oloṣu mẹjọ ti wọn ti gun le nitori awọn ẹtọ ti wọn n beere lọwọ ijọba, ṣugbọn ti wọn ko fun wọn. Lati alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹwaa yii, ni awọn oloye ẹgbẹ naa ti wọle ipade aṣedoru ti wọn ṣe.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i kede sita pe awọn ti figi gun iyanṣẹlodi ọhun, sibẹ, awọn ti wọn mọ bi nnkan ṣe n lọ ati ohun ti wọn fẹnu ko si nibi ipade to waye ni Sekiteriati wọn to wa niluu Abuja sọ pe, ki wọn kan sọrọ jade tabi ki wọn fi atẹjade sita lo ku, awọn olukọ naa ti fopin si iyansẹlodi wọn.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun yii, ni iyanṣẹlodi naa ti bẹrẹ latari atunṣe si owo-oṣu wọn, pipese awọn ohun eelo ti wọn fi le maa kọ awọn akẹkọọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ti wọn n beere lọwọ ijọba, eyi ti awọn mejeeji ko le fori ọrọ naa ti sibi kan pẹlu bi wọn ko ṣe gbọra wọn ye, ti ekinni ko si ṣetan lati tẹ fun ekeji.

Ṣugbọn ni bayii, o jọ pe ọrọ naa ti rodo lọọ mumi, awọn olukọ ti fẹẹ pada sileewe lati maa kọ awọn akẹkọọ wọn lọ.

Leave a Reply