Ẹgbẹ oṣẹlu PDP le ọmọ ẹgbẹ wọn danu l’Ekiti, wọn lo gbaṣẹ lọwọ Fayẹmi

Dada Ajikanje

Ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Ekiti ti fofin de Ọgbẹni Badejọ Anifowoṣe lori ẹsun pe o gbaṣẹ lọwọ Gomina Kayọde Fayẹmi.

Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o n ba ẹgbẹ mi-in ṣe wọle-wọde atawọn iwa mi-in to lodi si ofin ẹgbẹ.

Ninu ikede ti Akọwe ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Raphael Adeyanju, ẹka mi-in ninu ẹgbẹ oṣelu PDP fi sita, lo ti sọ pe ẹgbẹ naa fofin de Anifowose nitori to gba lati jẹ alaga fun ileeṣẹ to n ṣeto aabo fun awujọ nipinlẹ Ekiti ninu ijọba Kayọde Fayẹmi, eyi ti ẹgbẹ naa ko fọwọ si.

Adeyanju sọ pe igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ naa lo fẹnu ko lati fofin de e lẹyin ipade pajawiri ti alaga ẹgbẹ naa, Bisi Kọlawọle, pe ni kete ti awọn oloye ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọọdu ẹ, iyẹn Ikun Ward 01, ni Mọba, nipinlẹ Ekiti ti fọrọ ọhun to awọn leti.

Ak̀ọwe ẹgbẹ yii fi kun un pe awọn ti wọn jẹ oloye ni wọọdu ẹ ti kọkọ ṣagbekalẹ igbimọ ẹlẹni mẹta eyi ti Agbẹdẹ Sunday Afolabi jẹ alaga ẹ lati ṣewadii gbogbo ẹsun ti wọn fi kan Anifowoṣe, ṣugbọn ti ọkunrin naa ko yọju si wọn.

O ni ṣaaju asiko yii lawọn ọmọ ẹgbẹ naa ti n fura si ọkunrin yii gẹgẹ bii ẹni ti ẹgbẹ oṣelu APC n lo lati fi da ẹgbẹ awọn ru. O ni gbogbo ọna ni ẹgbẹ naa wa lati gbọ tẹnu ẹ, ki awọn too gbe igbesẹ, ṣugbọn toun paapaa ko bikita lati waa sọ tẹnu ẹ niwaju igbimọ ọhun.

Adeyanju sọ pe bo tilẹ jẹ pe ko si ẹṣẹ ninu ki eniyan sin ipinlẹ ẹ, sibẹ, PDP ko ni i gba awọn ọmọ ẹgbẹ ẹ nimọran lati darapọ mọ ijọba ti ko ni ohunrere kankan fun ipinlẹ naa.

O fi kun un pe latigba ti ijọba APC yii ti gba akoso l’Ekiti, ko ti i si iṣẹ gidi kan bayii to ṣe, ju bo ti ṣe n fojoojumọ naka ijakulẹ ẹ si ijọba PDP to kuro nipo ọhun. O ni, “Ti ọmọ ẹgbẹ wa ba tun lọọ darapọ mọ iru ijọba bẹẹ, dajudaju, wọn yoo tun maa sọ pe awa la o jẹ ki awọn ni aṣẹyọri kankan, bẹẹ wọn ko ni aṣeyọri gidi kan ti wọn fẹẹ ṣe tẹlẹ.”

Ṣa o, Anifowoṣe naa ti sọrọ, ohun to si sọ lori bi wọn ti ṣe fofin de e ninu ẹgbẹ ni pe igbesẹ wọn ọhun ko tọna rara.

O ni, “Ohun kan ti mo mọ ni pe ẹgbẹ oṣelu PDP meji la ni l’Ekiti, awọn ti wọn n halẹ kiri yii, emi ko si lọdọ wọn, bẹẹ lọrọ wọn paapaa ṣi wa nile-ẹjọ, wọn ko si laṣẹ lati le mi tabi sọ pe ki n kuro ninu ẹgbẹ fawọn. Ati pe emi ki i ṣe ara wọn.”

Leave a Reply