Ẹgbẹ oṣiṣẹ yari l’Ekiti, wọn lawọn o ni i gba ki Fayẹmi ge owo-oṣu awọn ku

Surdiq Taofeek, Ado-Ekiti

Ado-Ekiti

Apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Ekiti ti fi aake kọri pe awọn ko ni i gba ki Gomina ipinlẹ naa, Dokita Kayọde Fayẹmi, ge owo-oṣu awọn ku.

Bakan naa ni awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ naa tun kọ jalẹ pe awọn ko ni i gba ki ijọba ipinlẹ naa ṣe ayọkuro ninu owo-oṣu tuntun ti o jẹ ẹgbẹrun lọna igba naira ti ijọba ipinlẹ naa ṣẹṣẹ bẹrẹ si i san fun wọn.

Bẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni ijọba ipinlẹ naa ba gbogbo awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ipinlẹ naa ṣepade pe ijọba ipinlẹ naa ko ni i le maa san owo kan ti ijọba n san fun awọn ileeṣẹ ijọba ati awọn ajọ kọọkan ti o jẹ ti ijọba ni ipinlẹ naa.

Lọjọ ti gomina ba wọn ṣepade naa, gbogbo awọn ajọ to jẹ ti ẹgbẹ oṣiṣẹ ni wọn wa nibẹ. Gbogbo awọn olori oṣiṣẹ to wa nibi ipade naa ni wọn gba si ijọba lẹnu, ti wọn ko si gbe igbesẹ lati ta ko igbese tuntun tijọba gbe yii.

Ninu lẹta kan ti olori awọn oṣiṣẹ nipinlẹ naa, Ọgbẹni Kọlapọ Ọlatunde, kọ si gomina, lo ti pa a laṣẹ fun ijọba ipinlẹ naa pe awọn ko ni i gba igbesẹ tuntun ti ijọba ipinlẹ naa fẹẹ gbe.

Awọn oṣiṣẹ naa tun sọ ninu lẹta naa pe ijọba ko gbọdọ gbe igbesẹ kankan lati ge owo awọn oṣiṣẹ to wa ni akaso kẹtala ati akasọ kẹtadinlogun ti wọn ko ti i maa san owo-oṣu tuntun to jẹ ẹgbẹrun lọna ọgbọn naa fun ku.

Wọn ni gbogbo ọgbọn ti ijọba ipinlẹ naa n da lati ge owo-oṣu awọn oṣiṣẹ ku ni aṣiri rẹ ti tu si awọn lọwọ. Wọn ni ti ijọba ba fi le gbe igbesẹ naa, awọn yoo gun le iyanṣẹlodi, nitori awọn ko ni i gba ki ijọba fi owo-oṣu awọn jẹ awọn niya.

Leave a Reply