Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Ondo, to tun jẹ alaga gbogbo awọn gomina iha Guusu ilẹ wa, ati alaga gbogbo awọn gomina ilẹ Yoruba, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu, ti laago ikilọ pe gbogbo awọn to n sọrọ lodi si yiyi ipo agbara si agbegbe mi-in, tabi ki aarẹ ti yoo jẹ lẹyin Muhammadu Buhari wa lati iha Guusu ilẹ wa kan fẹẹ fọ Naijiria si wẹwẹ ni. Bẹẹ lo kilọ pe ẹgbẹ oṣelu ti ko ba fẹẹ fidi-rẹmi ninu eto idibo ọdun 2023, ma ṣe gbiyanju lati fa ondije fun ipo aarẹ kalẹ lati agbegbe Ariwa ti i ṣe Oke-Ọya ilẹ wa.
Amofin agba Akeredolu, la ọrọ yii mọlẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu keji yii, lọfiisi rẹ to wa nile ijọba ipinlẹ Ondo, l’Akurẹ, nigba to n gbalejo awọn aṣoju ẹgbẹ kan to n ja fun pinpin ipo agbara kiri agbegbe orileede wa, Power Rotation Movement (PRM).
Ọgbẹni Pogu Bitrus, to jẹ alaga ẹgbẹ awọn eeyan agbegbe Aarin-Gbungbun (Middle Belt Forum), lo ṣalaga ẹgbẹ PRM yii, oun lo si ko awọn mi-in sodi lọọ ṣabẹwo ọhun.
Akerodolu ni: “A ti ṣepade meji si mẹta, a o si fọrọ sabẹ ahọn sọ pe agbara gbọdọ bọ si iha Guusu lọtẹ yii. Ẹgbẹ oṣelu to ba ti ṣetan lati fidi-rẹmi nikan lo le mu ondije fun aarẹ lati iha Ariwa. Inu mi dun pe ẹyin ti ẹ jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu ọtọọtọ ti n ko ara yin jọ papọ lati fi igbanu kan ṣoṣo ṣọja bayii. Ohun ti gbogbo wa duro le lori ni ki eto pin-in-ire la-a-ire wa lori ipo aarẹ, ko ma si ojooro tabi ojuṣaaju. Ohun kan ṣoṣo to tọ, to si yẹ, ni pe lẹyin ọdun mẹjọ ti Ariwa fi ṣejọba, Guusu gbọdọ bọ sibẹ ni.
Awa kan gbagbọ pe ẹtọ ati ododo fidi mulẹ lorileede Naijiria. O nidii ta a fi gbagbọ bẹẹ, a si le gbeja igbagbọ wa. Awọn kan n jiyan pe ko pọn dandan ki aarẹ wa lati apa ibi kan, ko ṣaa ti jẹ eeyan gidi to kunju oṣuwọn la yan sipo lo ṣe koko. Mo fẹẹ bi wọn leere, ṣe eeyan to kunju oṣuwọn ko si lagbegbe Guusu ni?
Emi pẹlu awọn gomina ẹlegbẹ mi lati iha Guusu, gbogbo wa ti pinnu, a si ti ṣetan. Ẹni yoowu ta a ba fa kalẹ, ko saa ti jẹ eeyan Guusu, a maa gbaruku ti i. Ohun ta a ṣaa fẹ ni pe ki aarẹ bọ siha Guusu ni 2023. Awọn eeyan to le ṣe e, to kunju oṣuwọn wa ni agbegbe Guusu inu lọhun-un, tabi Guusu/Ila-Oorun, ibaa si jẹ Guusu/Iwọ-Oorun.
“Mo nifẹẹ si ẹgbẹ yin o, mo si maa ti yin lẹyin. Ẹ lọọ bẹrẹ si i ko awọn ọdọ jọ, ẹ maa ṣeto to yẹ, ko gbọdọ si magomago lasiko ibo yii, o daju pe a maa jawe olubori nigbẹyin. Kẹ ẹ si ba awọn obinrin naa sọrọ, ẹ fa wọn mọra, ki wọn kun wa lọwọ,” bẹẹ ni Akeredolu gunlẹ ọrọ rẹ.
Lara awọn mi-in to wa nibi abẹwo ọhun ni Kọmuredi Jare Ajayi, Alukoro fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, Ọnarebu Kenneth Robinson, to jẹ Alukoro fun ẹgbẹ ajijangba Niger-Delta (PANDEF), Ajagun-fẹyinti Collins Ihekire, to ṣoju fun ẹgbẹ awọn ẹya Igbo, Ohaneze Ndigbo, ati Abagun Kole Ọmọlolu, Akọwe eto Afẹnifẹre, titi kan Ọnarebu Ayọdele Oni to ṣoju fun ẹgbẹ awọn agbaagba Yoruba (YCE), ati awọn mi-in.