Ijọba Ọyọ fẹẹ yi orukọ Fasiti Ladoke Akintọla pada

Faith Adebọla

 

Bi nnkan ba lọ bo ṣe yẹ ko lọ, ko ni i pẹ rara ti ayipada yoo fi ba orukọ Fasiti Ladoke Akintọla, iyẹn LAUTECH, ti orukọ rẹ yoo si yi pada si LAU, iyẹn Ladoke Akintọla University.

Eyi wa ninu abadofin kan ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde atawọn ọmọ igbimọ rẹ fẹnu ko le lori, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu keji yii, lati fi ṣọwọ sawọn aṣofin ipinlẹ naa, ninu eyi tijọba ti n beere ifọwọsi wọn lati ṣatunṣe si fasiti ọhun, ki wọn si mu igbega ba a.

 

 

Lara atunṣe ti wọn fẹẹ ṣe si ofin to ṣe idasilẹ fasiti ọhun ni pe, awọn ẹkọ ti wọn yoo maa kọ nibẹ ko ni i jẹ ti imọ ẹrọ ati imọ ijinlẹ sayẹnsi nikan, ṣugbọn awọn akẹkọọ yoo bẹrẹ si i lanfaani lati gba imọ nipa awọn iṣẹ bii ibagbepọ ẹda, imọ ofin, iṣiro, ibanisọrọ ati bẹẹ bẹẹ lọ, gẹgẹ bo ṣe wa lawọn fasiti nla nla mi-in.

Abadofin naa, to ba ti bẹrẹ iṣẹ, yoo tun pese ilana to mọyan lori fawọn oṣiṣẹ-fẹyinti lati ri abojuto to peye gba lẹyin ifẹyinti wọn.

 

 

Atẹjade kan ti Akọwe iroyin fun gomina, Ọgbẹni Taiwo Adisa, fi lede lori ọrọ yii sọ pe:

“Ni pataki, ninu abadofin tuntun yii, a ti yi orukọ fasiti LAUTECH pada, Ladoke Akintọla University tabi LAU, la o maa pe e.

 

 

“Igbimọ alakooso ipinlẹ Ọyọ ti fọwọ si abadofin naa, a ti pari iṣẹ lori rẹ, a oo si fi i ṣọwọ sileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, kawọn aṣofin naa le ṣe ipa tiwọn lori ẹ, ki wọn si lu u lontẹ, lẹyin naa ni gomina yoo buwọ lu u, ti ofin naa yoo si bẹrẹ iṣẹ lẹyẹ-o-sọka,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply