Monisọla Saka
Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ mọnamọna jake-jado orilẹ-ede Naijiria, labẹ ẹgbẹ wọn ti wọn n pe ni National Union of Electricity Employee (NUEE), naa ti lawọn yoo darapọ mọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, Nigerian Labour Congress, (NLC), ninu iyanṣẹlodi wọn ti yoo bẹrẹ ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Ọrọ iyanṣẹlodi yii waye lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ninu atẹjade kan ti Dominic Igwebike, ti i ṣe akọwe ẹgbẹ naa buwọlu, latari owo iranwọ epo bẹntiroolu tijọba lawọn fẹẹ yọ.
Nibẹ ni wọn ti ni, “Pẹlu abajade ipade awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ, eyi to waye lọjọ keji, oṣu yii, nile ẹgbẹ wọn niluu Abuja, latari bi ijọba ṣe yọwo iranwọ epo lojiji, to si ti ko inira nla ati idaamu ba awọn araalu, eyi to mu ki gbogbo nnkan gbowo leri, ẹgbẹ oṣiṣẹ ti kede iyanṣẹlodi kaakiri ilẹ Naijiria, bẹrẹ lati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun yii.
Fun idi eyi, lati aago mejila oru ọjọ Wẹsidee yii nileeṣẹ mọnamọna yoo ti dawọ iṣẹ duro”.
Lati ọjọ kẹta ti aarẹ tuntun ti depo aṣẹ, iyẹn l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni ileeṣẹ epo rọbi nilẹ yii, NNPCL, ti kede owo ti wọn yoo maa ta epo lati Naira marundinlọgọta (195), to wa tẹlẹ, si aarin ọrinlenirinwo Naira (480), si ọrinlelẹẹẹdẹgbẹta Naira o din mẹwaa (570).
Wọn ni Aarẹ Tinubu ti yẹba adehun, nitori ti wọn yoo ba tilẹ yọwo iranwọ, ko yẹ ko jẹ lasiko yii rara. Wọn ni loootọ ni Aarẹ Muhammadu Buhari ti kọkọ sọ tẹlẹ pe awọn yoo yọwo iranwọ ori epo nipari oṣu Kẹfa, nitori bi ko ṣe si ninu aba eto iṣuna ọdun 2023. Ṣugbọn ti Tinubu ti wọn bura wọle fun lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, sọ ninu ọrọ akọsọ ẹ pe ko sohun to n jẹ owo iranwọ mọ, ọrọ to sọ yii lo bi wahala laarin ilu pẹlu bawọn elepo ati ọlọja ṣe sọ nnkan ti wọn n ta di goolu lojiji tawọn araalu n pariwo pe ijọba ko wa ọna abayọ silẹ ki wọn too kede owo iranwọ ti wọn lawọn ko ni i san mọ. Nigba tawọn oṣiṣẹ si n gbaradi fun iyanṣẹlodi lọwọ, awọn oniṣẹ mọnamọna naa lawọn ti ṣetan lati sọ gbogbo ilu sinu okunkun birimu, nitori awọn naa yoo kopa ninu iyanṣẹlodi ọhun.