Ẹgbẹ okunkun ti wọn n ṣe sọ awọn mọkanla dero ahamọ!

Gbenga Amos, Ogun

 Bawọn mọlẹbi gende mọkanla yii ba n wa wọn, wọn o le ri wọn nigboro lasiko yii o, tori awọn afurasi naa ti ko sakolo ọlọpaa ipinlẹ Ogun lọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa yii, wọn lọmọ ẹgbẹ okunkun to n da’lu laamu ni wọn, wọn si ti mu wọn. Lasiko ti wọn n ṣepade ẹgbẹkẹgbẹ wọn lọwọ ni Ojule kẹtala, Opopona Agọ Adura, niluu Ijoko, nijọba ibilẹ Ifọ, lọwọ tẹ wọn.

Orukọ awọn kọlọransi ẹda ọhun ni Moshood Owolabi, Ọlayẹmi Arukudu, Yusuf Ọlajide, Ibukun Adeoye, Yọmi Samson, Faruk Salami, Olukunle Isaac, David Nwuzor, Nwanah Samuel, Ganiyu Ogunrinde, atẹnikan to ni Chukwuemeka lasan loun n jẹ.

Olobo kan lo ta ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Sango Ọta, nigba tẹnikan pe wọn sori aago pe awọn araabi yii ti n kora jọ lati ṣepade wọn. Lọgan ni DPO teṣan naa, SP Dahiru Saleh, ti ke sawọn ọmọọṣẹ rẹ atawọn ẹṣọ alaabo Amọtẹkun to wa nitosi, awọn ẹṣọ So-Safe kan naa tẹle wọn, ni wọn ba ya bo wọn, ọwọ ba meje ninu wọn, awọn meloo kan raaye ta kọṣọ sigbo, wọn si juba ehoro lẹsẹkẹsẹ.

Awọn aladuugbo kan ni wọn ran awọn agbofinro lọwọ tọwọ fi pada ba mẹrin lara awọn to sa lọ ọhun.

Alakoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, to fiṣẹlẹ yii to ALAROYE leti lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, sọ pe awọn afurasi ọhun ti jẹwọ pe ni tododo, ọmọ ẹgbẹ Aiye lawọn.

Lara ẹru ofin ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni egboogi oloro ti wọn n pe ni igbo, wọn tun ba eyi ti wọn n pe ni Colorado ati Bonky pẹlu.

Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe ki wọn ko awọn afurasi naa lọ sọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ lẹka ti wọn ti n gbogun ti ẹgbẹ okunkun ṣiṣe atiwa ọdaran. O ni lẹyin iwadii ijinlẹ, ilẹ-ẹjọ lọrọ kan fun wọn.

Leave a Reply