Ni gbara ti wọn ti di ibo apapọ tan laarin ipari ọdun 1964 si ibẹrẹ ọdun 1965, ti ọrọ naa mi logbologbo, ṣugbọn ti aarẹ Naijiria, Oloye Nnamdi Azikiwe, pe Alaaji Tafawa Balewa pe ko waa bẹrẹ ijọba rẹ tuntun, ere mi-in to ku lati sa bayii ni ere ibo ti wọn yoo di ni Western Region lọdun naa. Ohun ti ẹgbẹ Action Group ro kọ lo ṣẹlẹ, ṣe wọn ti ro pe awọn ati ẹgbẹ NCNC (ti wọn jọ pawọ pọ di ẹgbẹ UPGA) yoo le gba ijọba kuro lọwọ ẹgbẹ awọn ara ilẹ Hausa ti wọn n pe ni NPC, ati ẹgbẹ Dẹmọ ti Oloye Ladoke Akintọla ti wọn jọ n ṣe ẹgbẹ NNA, ṣugbọn nigba ti wọn dibo tan ti kinni naa ko ri bẹẹ mọ, kaluku pada si aaye rẹ, ẹgbẹ Action Group pada da duro, NCNC da duro, o si jọ pe o tun di asiko ibo mi-in ki ajọṣepọ kankan too tun waye. Ṣugbọn kinni kan wa ti ẹgbẹ Action Group, ẹgbẹ Ọlọpẹ fẹẹ ṣe, iyẹn naa ni lati wa gbogbo ọna lati gba ijọba Western Region kuro lọwọ Akintọla.
Ẹgbẹ Action Group ti ro pe bo ba jẹ awọn lawọn wọle lasiko idibo to kọja naa ni, irọrun ni yoo jẹ fawọn lati yọ olori ẹgbẹ awọn, Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ, kuro ninu ẹwọn ti ijọba apapọ ju u si. Ṣugbọn nigba ti wọn ko ti wọle, ibi ti iṣẹ ku si ni lati gba ijọba Western Region kuro lọwọ ẹgbẹ Dẹmọ, ki awọn si lo agbara ijọba West yii lati fi mu ijọba apapọ nipa, ki wọn yọ olori awọn jade. Nibi ti iṣẹ tun ti bẹrẹ niyi, nitori ọrọ naa dun i sọ lẹnu ni, ko ya bẹẹ. Akintọla nikan, gẹgẹ bi olori ijọba lo lẹtọọ ati aṣẹ lati tu ile-igbimọ aṣofin West ka, ko si da ọjọ idibo tuntun, bi wọn ṣe n ṣe e nigba naa niyẹn. Bi olori ijọba ba tu ile-igbimọ ka bayii, wọn yoo tun dibo tuntun mi-in lati yan awọn aṣofin ọmọ ile-igbimọ, ẹgbẹ oṣelu to ba si ni aṣofin to pọ ju lọ nile yii naa ni yoo fa Purẹmia, olori ijọba kalẹ, ohun ti ibo naa ṣe ṣe koko ree.
Nigba to ti jẹ1960 ni wọn dibo tuntun to kọkọ gbe Akintọla wọle labẹ asia ẹgbẹ AG, dandan ni ki ibo waye ni 1965, ṣugbọn ọrọ naa le ju oju tawọn eeyan fi n wo o lọ. Akintọla mọ pe awọn eeyan koriira ẹgbẹ Dẹmọ, iyẹn ẹgbẹ oṣelu rẹ, bẹẹ naa ni wọn koriira awọn oloye ẹgbẹ ọhun, afi ki wọn wa ọna ti inu awọn eeyan yoo fi rọ ki wọn too ṣeto ibo tuntun, bi bẹẹ kọ, wọn yoo fi ibo le oun Akintọla kuro nile ijọba. Bẹẹ awọn ọmọ ẹgbẹ AG ko fẹẹ gba bẹẹ, wọn ni ki Akintọla tu ile ka lẹsẹkẹsẹ, ko jẹ ki awọn waa dibo mi-in, kawọn le mọ ẹni ti awọn araalu n fẹ ninu ẹgbẹ Dẹmọ ati ẹgbẹ Ọlọpẹ, wọn ni bi wọn ba dibo, bo ba jẹ Akintọla lo wọle, ti ibo naa ko si ni ojooro ninu, awọn yoo gba a lọgaa, ṣugbọn bo ba jẹ AG lo wọle, koun naa mọ pe AG lọga oun, ko si gbe ijọba silẹ wọọrọwọ, ko maa ba tirẹ lọ.
Akintọla gbọ ni, ko gba. O mọ pe dandan ni ki awọn dibo lasiko yii tootọ, iyẹn lọdun 1965, ṣugbọn o fẹ ki ohun gbogbo ti bọ si oun lọwọ ki awọn too ṣe bẹẹ, nitori bi ko ba ṣe bẹẹ, ọrọ naa le yiwọ, ko waa di pe ẹni to ti wa ninu ọgba tẹlẹ yoo di ọmọ ẹyin ọgba, ti wọn yoo le e jade nibi to ti ro pe ile baba oun ni. Ohun gbogbo rọ Akintọla lọrun nigba ti wọn n dibo ti ijọba apapọ, Sardauna Ahmadu Bello ṣeto owo fun wọn, wọn ṣeto ṣọja, wọn ṣeto ọlọpaa, wọn ṣeto awọn adajọ ti yoo dajọ pajawiri, wọn ṣeto awọn wolewole, wọn si faṣẹ ijọba apapọ si ọwọ Akintọla pe ohun yoowu to ba ṣe lasiko naa, aṣegbe ni, dandan ni ki ẹgbẹ NNA, ẹgbẹ awọn Sardauna yii wọle. Ṣugbọn Akintọla ko mọ boya iru ohun to ṣẹlẹ nigba ibo apapọ yii yoo ṣẹlẹ lasiko ti awọn ba fẹẹ di ibo tawọn, iyẹn ibo ti Western Region.
Oun naa mọ pe bi Sardauna ko ba fun oun ni iru agbara to fun oun lasiko ibo apapọ yii, to ba jẹ kidaa agbara toun loun fẹẹ lo ni West, o ṣee ṣe ki ẹgbẹ Dẹmọ ja bọ, ki wọn fidi rẹmi, bi ẹgbẹ naa ba si fi le ja bọ lasiko idibo, Akintọla funra ẹ lo ja bọ. Ki eyi ma baa ri bẹẹ, ọkunrin oloṣelu nla igba naa mura lati wa nnkan ṣe si i. Oun naa mọ ohun to n bi awọn ara West ninu, o mọ pe ọrọ Awolọwọ ni, bi oun ba mọ ọrọ ti oun yoo sọ fun wọn ti wọn yoo fi ro pe oun n ṣiṣẹ lati ri i pe Awolọwọ jade lẹwọn, o mọ pe awọn Yoruba le fi ori ji oun, ki wọn si tori rẹ tẹle oun titi ti awọn yoo fi dibo tan. Loootọ ni kinni naa, Akintọla naa mọ, ṣugbọn bi ọrọ oṣelu ba ti da bayii, etekete ati ọgbọn buruku pẹlu ẹtan lawọn oloṣelu fi n ba awọn eeyan ṣe. Akintọla mọ pe to ba jẹ oun loun bẹrẹ ọrọ yii, awọn eeyan ko ni i gba, wọn yoo sọ pe irọ ni, nitori ẹ lo ṣe dẹ awọn ọmọ Ẹgbẹ Ọlọfin si wọn.
Ẹgbẹ Ọmọ Ọlofin yii, ẹgbẹ ti awọn agbaagba Yoruba kan da silẹ ni, ṣugbọn awọn agbaagba ti wọn da a silẹ yii, pupọ ninu wọn ko fẹran Awolọwọ, wọn fẹẹ fi ẹgbẹ naa pa irawọ rẹ ni. Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa lo wa tẹlẹ, ṣugbọn nitori pe atilẹyin ẹgbẹ yii lo fun ẹgbẹ oṣelu Action Group lagbara nilẹ Yoruba, ti wọn si mọ pe Awolọwọ ni oludasilẹ ẹgbẹ naa, tirẹ ni ọpọ awọn ti wọn wa ninu ẹgbẹ yii n ṣe, awọn kan dide, wọn da ẹgbẹ mi-in silẹ, wọn ni ẹgbẹ ọmọ Yoruba ti ko ni i ṣe oṣelu ni, ati pe orukọ ẹgbẹ naa ni ẹgbẹ Ọmọ Ọlọfin. Ẹni to ṣe alaga igbimọ ẹgbẹ yii, Moses Adekoyejọ Majẹkodunmi, ọrẹ awọn Balewa ni, ọrẹ awọn Akintọla. Oun nijọba Balewa gbe akoso Western Region le lọwọ, lẹyin ti wọn ti fi ipo agba gba a lọwọ ẹgbẹ AG. Asiko to n ṣejọba yii ni wọn ṣa iwe jọ ni West, ti wọn ni Awolọwọ ko owo kan jẹ, lẹyin naa ni wọn gbe ẹjọ pe o fẹẹ fi ipa gbajọba dide, bi wọn si ti sọ Awolọwọ sẹwọn ko ṣẹyin iru wọn.
Nitori bẹẹ , ko ya ẹnikẹni lẹnu pe bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ Ọmọ Ọlọfin sọ pe awọn ko ni i ṣe oṣelu, ẹyin Akintọla ni wọn n wa ni gbogbo igba, oun si ni agbojule Akintọla nile ijọba. Nigba ti ọrọ ibo si fẹẹ ṣẹlẹ yii, ti Akintọla ko si mọ bi ifa oun yoo fọre tabi ko fọre, ọdọ ẹgbẹ Ọlọfin lo sa pamọ si. Ẹgbẹ naa jade ni ọjọ kọkanlelogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 1965, lẹyin ti wọn ti yanju ọrọ idibo apapọ to fẹẹ da wahala silẹ, wọn ni awọn ti ṣetan bayii lati pari ija laarin Awolọwọ ati Akintọla, kawọn si ṣiṣẹ lori bi Awolọwọ yoo ṣe jade ni ahamọ to wa. Majẹkodunmi funra rẹ lo fọwọ si iwe yii, oun ati akọwe ipolongo wọn, Ọmọọba Michael Ogun, awọn mejeeji to jẹ ni gbogbo asiko yii, ọta Awolọwọ ni wọn n ṣe. Ohun ti ọrọ wọn ko si ṣe ta naa ree, to jẹ niṣe ni awọn ọmọ ẹgbẹ Ọlọpẹ ya wọn balẹ bi agbado.
Akọwe ipolongo ẹgbẹ AG, Ọgbẹni Bọla Ige, lo gbe iwe jade lẹsẹkẹsẹ ti awọn Ẹgbẹ Ọmọ Ọlọfin sọrọ wọn sita. O ni ko si ẹni to bẹ awọn ọmọ ẹgbẹ yii niṣẹ ti wọn fẹẹ jẹ yii o, nitori gbogbo eeyan lo mọ ibi ti wọn fi si, wọn si mọ pe idunnu wọn lo jẹ pe Awolọwọ wa lẹwọn, bi ko si ṣe ni i jade sita jẹ ohun itẹlọrun fun wọn. O ni ko sọmọ ẹgbẹ AG kan, tabi awọn alatilẹyin ẹgbẹ Ọlọpẹ ti yoo ba wọn ṣepade kankan nibẹ, ibi yoowu ti wọn ba pe ipade ipari ija si laarin Awolọwọ ati Akintola, funra wọn ni wọn yoo wa nibẹ. Bọla Ige ni ki lo de to jẹ nigba ti wọn pari ibo lawọn yii fẹẹ ṣẹṣẹ pari ija, paapaa nigba ti wọn mọ pe ibo Western Region lo kan. O ni bi ẹgbẹ naa ba jẹ ẹgbẹ oloootọ to fẹẹ ṣe deede, ti ko si lẹyin Akintọla, ohun to yẹ ki wọn sọ ni pe ki Akintọla tu ile-igbimọ ka bayii, ko si dajọ ibo tuntun, ki awọn eeyan West le yan ijọba ti wọn fẹ funra wọn.
Ọrọ naa jo awọn ẹgbẹ Ọmọ Ọlofin lara, o ka Akintọla paapaa lara, nitori ibi ti wọn foju si, ọna ko ba ibẹ lọ, ko si ohun ti ọkunrin olootu ijọba West naa le ṣe ju ki wọn bẹrẹ si i palẹmọ ibo tuntun lọ, nitori bi wọn ko ba ṣe bẹẹ ni tootọ, ọrọ naa yoo di ariwo