Faith Adebọla
Ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, Christian Association of Nigeria (CAN) , ti laago ikilọ setiigbọ awọn oloṣelu lasiko yii pe awọn o ni i fara mọ oludije dupo aarẹ to jẹ ẹlẹsin Musulumi to ba fi ẹlẹsin Musulumi bii tiẹ ṣe igbakeji, wọn lawọn o ni i dibo fun iru oludije bẹẹ.
Ẹgbẹ naa ni yatọ si pe awọn ko ni i ṣatilẹyin kankan fun iru awọn oludije ẹlẹsin kan naa bẹẹ, wọn ni ọrọ naa le da iyapa silẹ lorileede yii, o si le jẹ ki gbogbo nnkan dojuru kọja atunṣe.
Agbẹnusọ fun Aarẹ ẹgbẹ CAN, Rẹfurẹndi Bayọ Ọladeji, lo sọrọ yii di mimọ laarin ọsẹ yii nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ. O ni ẹgbẹ CAN ti pinnu lati kọyin patapata si ẹni to ba daṣa aarẹ ati igbakeji ẹ ti wọn jẹ ẹlẹsin kan naa.
Ọladeji ni: “Awọn oloṣelu le sọ ọrọ oṣelu wọn bi wọn ṣe fẹ o, ṣugbọn awa ti sọ tiwa. Ẹgbẹ to ba fa aarẹ ati igbakeji aarẹ ẹlẹsin Musulumi kan naa kalẹ, bo si jẹ ẹlẹsin Kirisitẹni kan naa ni, ẹgbẹ naa maa fidi rẹmi ni. Ọdun 1993 kọ la wa yi. Lasiko yii ti aarẹ jẹ Musulumi, ti igbakeji ẹ si jẹ Kiristiẹni, oju wa ṣi n ri mabo. Ọlọrun nikan lo le sọ iye awọn ẹlẹsin Kirisitẹni ti wọn ti da ẹmi wọn legbodo.
“Ki lẹ waa ro pe yoo ṣẹlẹ to ba lọọ jẹ ẹlẹsin Musulumi lawọn mejeeji ti wọn wa nipo agbara aarẹ? Ọrọ naa maa buru gidi ni o. Ofin ilẹ wa sọrọ nipa igbelarugẹ awọn ẹsin lọgbọọgba.
“Ẹgbẹ to ba fẹẹ gbiyanju ẹ wo, lati fa aarẹ ati igbakeji ẹlẹsin kan naa kalẹ, ẹ jẹ ki wọn gbidanwo ẹ na, igba yẹn ni wọn maa mọ pe awa Kirisitẹni ko ṣee fọwọ rọ sẹyin rara.
“Gbogbo wa la jọ ni orileede yii. Ti wọn ba gbiyanju ẹ wo, wọn maa jẹ iyan wọn niṣu.
“Abiọla ati Kingibe tawọn kan n pariwo pe wọn ti ṣe bẹẹ ri, ẹ bi wọn leere pe ibo ni wọn ba yara ja. Bẹẹ igba yẹn niyẹn o, ẹ jẹ kawọn tode oni yii dan an wo, wọn maa dan an tan ni.”
Bẹẹ ni ẹgbẹ CAN ṣekilọ.