Ẹgbẹ onimọto Ọyọ: Makinde yan Ọmọlẹwa, Tokyo, Ejiogbe rọpo Auxiliary

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti yan awọn eeyan tuntun sinu igbimọ alamoojuto ibudokọ gbogbo nipinlẹ Ọyọ.

Alhaji Tọmiwa Ọmọlẹwa lo yan gẹgẹ bii alaga igbimọ alamoojuto awọn awakọ ero ti wọn n pe ji Park Management System (PMS) bayii.

Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, lakọwe iroyin Gomina Makinde, Pasitọ Sulaiman Ọlanrewaju, kede igbesẹ naa.

Alaga ẹgbẹ awọn awakọ ero nigba kan ri, Alhaji Abideen Ejiogbe, ni wọn yan gẹgẹ bii igbakeji alaga akọkọ; wọn yan Ọgbẹni Ganiyu Mojeed gẹgẹ bii ọmọ igbimọ awọn agba kin-in-ni; Alhaji Musa Alubankudi gẹgẹ bii ọmọ igbimọ awọn agba ẹgbẹ awakọ keji; Alhaji Rahman Akinṣọla Tokyo, (atọpinpin eto iṣuna keji) Auditor; nigba ti Alhaji Wasiu Emiọla jẹ alukoro

Orukọ awọn ọmọ igbimọ ọhun yooku ni Alhaji Tajudeen Jimoh, (igbakeji alaga), Kamardeen Idowu (akapo); Tirimisiyu Olowopọsi (akọwe eto iṣuna); Abass Amolese (akọwe awọn eto gbogbo) ati Alhaji Hamidu Mustapha, ẹni tawọn eeyan ẹ tun mọ si Wẹrẹ, gẹgẹ bii atọpinpin eto iṣuna.

Gbogbo ibudokọ to wa n’Ibadan nijọba ti ti pa tẹlẹ latari wahala tawọn ọmọ ẹyin alaga igbimọ alakooso awọn awakọ ipinlẹ yii tẹlẹ, Alhaji Mukaika Lamidi (Auxiliary), ti wọn rọ loye fa laarin ọjọ mẹrin lẹyin ti ipo naa bọ mọ wọn lọwọ.

Ṣugbọn ni kete ti ijọba ṣagbekalẹ igbimọ apaṣẹ lo ti ni ki wọn ṣi gbogbo ibudokọ ti wọn ti pa silẹ, ti awọn ọmọ igbimọ yii si ti bẹrẹ iṣẹ lọjọ, Aje, Mọnde, ọjọ  karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹfa yii, nijọba ṣepade pẹlu gbogbo awọn to lẹnu ninu iṣẹ awakọ ẹrọ ipinlẹ Ọyọ, ti gbogbo wọn si fẹnu ko lati ṣiṣẹ papọ fun ilọsiwaju ipinlẹ yii.

Nigba to n fẹmi imoore rẹ han si Gomina Makinde fun iyansipo naa, Alhaji Ọmọlẹwa, alaga awọn awakọ ero ti wọn ṣẹṣẹ yan sipo yii sọ pe, “mo ṣetan lati mu ayipada rere ba ọna ti awa awakọ ero ipinlẹ yii n gba ṣiṣẹ, mọ si ṣeleri pe alaafia yoo jọba lasiko temi”.

 

Leave a Reply