Ẹgbẹ PDP da Ayu gunlẹ, wọn yan Damagum ni adele alaga wọn

Ọrẹoluwa Adedeji

Ilẹkẹ ma ja sile, ma ja sita, ibi kan ni ilẹkẹ naa yoo ṣaa ja si, ṣugbọn ilẹkẹ ọhun ti pada ja sibi kan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP bayii pẹlu bi wọn ṣe fidi alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ, Iyorchia Ayu, gunlẹ, ti wọn si ti yan adele alaga mi-in ti yoo maa tukọ ẹgbẹ naa.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta yii, ni wọn kede Umar Damagum, gẹgẹ bii Adele Alaga ẹgbẹ wọn.

Umar to jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ naa lapapọ lati iha Ariwa ni yoo wa ni ipo naa titi ti ile-ẹjọ yoo fi gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ ti wọn pe ta ko ọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Benue naa pe ko yee pe ara rẹ ni alaga ẹgbẹ PDP, niwọn igba ti wọn ti jawee gbele-ẹ fun un lati wọọdu rẹ, eyi ti ile-ẹjọ si ti sun si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii, ni awọn eeyan wọọdu agbegbe ti Ayu ti wa, iyẹn Wọọdu Igyorov, nijọba ibilẹ Gboko, nipinlẹ Benue, kede pe awọn ti jawee gbele-ẹ fun un.

Ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin naa ni pe o n ṣe ẹsẹ-kan-ile ẹsẹ-kan-ode ninu ẹgbẹ naa, bẹẹ lo si n ṣe agbodegba fun ẹgbẹ alatako. Bakan naa ni wọn ni ọkunrin naa ko san gbogbo awọn owo ẹgbẹ to yẹ ko san ni ibamu pẹlu ofin ati agbekalẹ ẹgbẹ PDP.

Ẹsun mi-in ti wọn tun fi kan an ni pe o ṣiṣẹ ta ko ẹgbẹ naa ni wọọdu rẹ, bẹẹ ni ko si tun dibo lasiko idibo gomina ati ileegbiomọ aṣofin to kọja yii. Wọn ni iwadii awọn fi han pe ọpọlọpọ awọn to sun mọ Ayu lo ṣiṣẹ ta ko ẹgbẹ PDP ni wọọdu rẹ, eyi to fa a ti ẹgbẹ naa ko fi rọwọ mu lasiko idibo to kọja nipinlẹ naa.

Ofin ti wọn fi de e ninu ẹgbẹ ni wọọdu rẹ yii ni ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Terhinde Utaan, funka mọ to fi gbe alaga naa ati ẹgbẹ PDP lọ si ile-ẹjọ Majisireeti kan to wa niluu Benue, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta yii, pe ki adajọ da a pe ki ọkunrin naa yee pe ara rẹ ni alaga ẹgbẹ naa mọ, niwọn igba ti wọn ti jáwé lọọ jokoo sile fun un.

Bo tilẹ jẹ pe Ayu da wọn lohun pe awada ni awọn ti wọn sọ pe wọn fidi oun gunlẹ ninu ẹgbẹ naa n ṣe, to sọ pe awọn oloye apapọ ẹgbẹ kan lo wa nidii wahala naa, ile-ẹjọ ko fakoko ṣofo rara ti wọn fi gbọ ẹjọ naa, ti Onidaajọ W. I Kpochi, fi sọ pe bi wọn ṣe fofin de alaga naa ṣi wa bẹẹ titi di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin yii, ti igbẹjọ yoo bẹrẹ lori rẹ.

Ẹni a fẹẹ sun jẹ lọrọ Ayu, to fepo para, to waa jokoo sẹgbẹẹ aaro. Ẹgbẹ PDP naa ko ro o lẹẹmeji rara ti wọn fi lo anfaani idajọ naa lati kede pe ki ọkunrin naa yẹba gẹge bii alaga titi ti idajọ yoo fi waye lori ẹjọ ti wọn pe ta ko alaga tẹlẹ naa ati ẹgbẹ PDP.

Oju-ẹsẹ naa ni wọn si ti kede adele alaga wọn, iyẹn Umar Damagum. Wọn ni oun ni ko maa tukọ ẹgbẹ yii lọ.

Tẹ o ba gbagbe, latigba ti wọn ti pari idibo abẹlẹ ẹgbẹ naa, ti wọn si fa Atiku Abubakar kalẹ gẹgẹ bii oludije wọn funpo aarẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ kan ti n sọ pe ki ọkunrin naa fi ipo alaga silẹ ki ofin pin-in-re, la-a-re ti ẹgbẹ naa n lo le ṣiṣẹ. Eyi ni pe ko ni i daa ko jẹ ati oludije funpo aarẹ ati alaga ẹgbẹ yoo wa lati agbegbe kan naa.

Ṣugbọn titi ti wọn fi dibo ni wọn ko ri ọrọ naa yanju, nitori olowo Ayu ni oun ko ni i jẹ ooro gan, bẹẹ ni iwọfa awọn ọmọ ẹgbẹ kan naa ni awọn ko ni i jẹ agunmatẹ. Eyi ni wọn si fa titi ti ibo aarẹ ati ti gomina fi waye, ti ẹgbẹ PDP si fidi-rẹmi lawọn ibi to ti yẹ ki wọn rọwọ mu to ba ṣe pe ko si ija kankan laarin wọn.

Lara awọn ti inu wọn dun si bi wọn ṣe fofin de Ayu ni Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ẹni to ṣiwaju awọn gomina maraarun ti wọn faake kọri pe awọn ko ni i ṣatilẹyin fun Atiku ti ko ba yọ Ayu.

Ọkunrin naa sọ niluu Portharcourt, ni ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pe igbesẹ to daa gba a ni bi wọn ṣe jawe gbele-ẹ fun alaga yii. Gomina naa ni ko ni i bojumu ki ẹni to padanu wọọdu rẹ lasiko idibo, ti ko mu ijọba ibilẹ ati ipinlẹ rẹ tun jokoo sibi kan ko sọ pe oun loun yoo maa dari ẹgbẹ.

O ni eyi ti Ayu iba fi lo ipo rẹ lati jẹ ki ẹgbẹ naa wa ni iṣọkan, niṣe lo jẹ ki ẹgbẹ naa yọ bọ lọwọ rẹ nipinlẹ Benue.

Ṣa, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin ti igbẹjọ mi-in yoo waye ni wọn n duro de lati mọ boya Ayorchia Ayu naa ni yoo maa tukọ ẹgbẹ PDP lọ tabi wọn yoo yan ẹlomi-in. Ṣugbọn gbogbo nnkan ṣe wa lọwọlọwọ yii, idaamu gidi wa fun Ayu, alaga PDP tẹlẹ.

Leave a Reply