Ọlawale Ajao, Ibadan
Ipinya ti de laarin Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ati Igbakeji rẹ, Ẹnjinnia Rauf Ọlaniyan.
Eyi ko ṣẹyin bi gomina ti awọn eeyan tun n pe ni GSM yii ṣe ja igbakeji rẹ naa silẹ gẹgẹ bii ẹni ti yoo lo ninu idibo gomina ipinlẹ naa lọdun 2023.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, alaga ileeṣẹ to n ri si ọrọ ile gbigbe nipinlẹ Ọyọ, Amofin Bayọ Lawal, ni Makinde mu gẹgẹ bii igbakeji rẹ tuntun fun idibo ọdun to n bọ.
Iyẹn ni pe, bi GSM ba wọle fun iṣejọba saa keji ninu idibo ọhun, Ọlaniyan ko ni i pada sọfiisi igbakeji gomina to wa lọwọlọwọ bayii.
O pẹ ti awọn eeyan ti n hu u gbọ labẹlẹ, ti awọn oniroyin si n gbe e jade pe aarin gomina ipinlẹ yii pẹlu igbakeji rẹ ko gun mọ, ṣugbọn ti awọn mejeeji yii n ta ko iroyin naa, wọn ni ifẹ ẹlẹyẹle, ifẹ aiṣẹtan, to wa laarin awọn ṣi wa sibẹ.
Ṣugbọn nigba to jọ pe nnkan ti bọwọ sori tan l’Ẹnjinia Ọlaniyan ṣẹṣẹ n fi ẹna sọrọ pe nnkan ko lọ deede mọ laarin oun atọga ẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii oṣu kan sẹyin nigbakeji gomina yii sọ ni gbangba pe nitori pe wọn ko pe oun si nnkan ẹgbẹ oṣelu PDP mọ lawọn eeyan ki i ṣee ri oun nibi awọn nnkan ti ẹgbẹ oṣelu naa n ṣe lẹnu ọjọ mẹta yii.
O fi kun un pe o ṣee ṣe ki oun paapaa dupo gomina nitori ẹgbẹ oṣelu marun-un ọtọọtọ lo ti n pe oun lati waa dara pọ mọ awọn, ati pe mẹta ninu wọn lo ṣetan lati fa oun kalẹ gẹgẹ bii oludije fun ipo gomina wọn.
Ni bayii ti Ẹnjinnia Makinde ti fọwọ osi juwe ile fun Ẹnjinnia Ọlaniyan pe oun ko nilo rẹ mọ ninu ijọba oun ni saa to n bọ, igbesẹ ti igbakeji gomina naa yoo gbe lasiko eto oṣelu to n lọ lọwọ yii lẹnikan ko ti i le sọ.