Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ, Sẹnetọ Rabiu Musa Kwankwaso, ti sọ pe ko si iyatọ ninu ọmọ to n jẹ eeru ati eyi to n jẹ yeepẹ lọrọ ẹgbẹ oṣelu meji to tobi ju lọ lorileede yii, iyẹn All Progressives Congress (APC) ati Peoples Democratic Party (PDP). O lawọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji ni wọn ti ja Naijiria atawọn eeyan inu rẹ kulẹ, tori naa, niṣe lo yẹ kawọn ẹgbẹ mejeeji lọọ fẹyinti na.
Kwankwaso ni oun atawọn ọrẹ oun, pẹlu awọn alatilẹyin awọn ti da ẹgbẹ kan to maa di ẹgbẹ oṣelu nla kẹta silẹ, yatọ si APC ati PDP, The National Movement (TNM) lo pe orukọ ẹgbẹ naa.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejilelogun, oṣu keji yii, ni Kwankwaso sọrọ yii nibi ifilọlẹ ẹgbẹ TNM ọhun, eyi to waye niluu Abuja. Bakan naa lo tun awọn ọrọ rẹ sọ lori eto Tẹlifiṣan Channels to waye lẹyin ayẹyẹ ifilọlẹ ọhun.
Lara awọn to pe ni ọrẹ rẹ ti wọn jọ ṣefilọlẹ ẹgbẹ tuntun naa ni minisita fun ere idaraya ati ọrọ ọdọ nigba kan, Solomon Dalung, awọn alẹnulọrọ lagbo oṣelu ilẹ Ariwa kan, Buba Galadima, Tanko Yakassai ati awọn gomina tẹlẹ mi-in bii Murtala Nyako tipinlẹ Adamawa, Lucky Igbinedion ti Edo ati Achike Udenwa, gomina ipinlẹ Imo nigba kan.
Kwankwaso ni: “A ṣepinnu yii gẹgẹ bii ọmọ Naijiria, paapaa awa ti ọrọ ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria n kọ lominu, nipa iṣejọba wa, eto oṣelu wa, aabo to mẹhẹ gidigidi, eto ẹkọ ti ko lọ geere ati igbaye-gbadun awọn araalu ti ko si.
“Ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP to wa ninu ẹgbẹ tuntun yii ni mi, bẹẹ la ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, ti APGA (All Progressives Grand Alliance), ati awọn ẹgbẹ oṣelu mi-in, bẹẹ la si ni awọn eekan eekan ti wọn ki i ṣe oloṣelu, lẹka eto ẹkọ, ọrọ-aje, ilera ati ikansira-ẹni, laarin wa.
“Ka sọrọ sibi tọrọ wa, mo gbagbọ pe ati ẹgbẹ oṣelu APC, ati PDP, wọn ti ja Naijiria kulẹ. A ni awọn idojukọ to lagbara gidi. Ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni mi lọdun 1998 nigba ta a da ẹgbẹ naa silẹ, lọdun 1999 ni mo jẹ gomina ipinlẹ Kano, mo tun ṣe minisita eto aabo, ati ti ajọ Naija Dẹlita, ti mo ṣoju awọn eeyan Ariwa/Iwọ-Oorun ninu ajọ naa.
A ti ri i pe awọn ipenija yii beere pe ka ṣe awọn atunṣe si aṣiṣe wa. Idi niyẹn lọdun 2015 ti emi atawọn eeyan kan fi para pọ da ẹgbẹ APC silẹ, a si ṣiṣẹ gidigidi lati jẹ ki ẹgbẹ naa rọwọ mu pẹlu erongba pe ayipada rere yoo wa lorileede yii, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe ibi ta a foju si, ọna ko gbabẹ, koda awọn eeyan tun waa gbagbọ pe PDP ṣi dara ju eyi lọ.”
Kwankwaso ni ẹgbẹ tuntun tawọn da silẹ yii, maa gba iṣakoso lọwọ APC lọdun 2023, ṣugbọn oun o ti i fẹẹ sọ hulẹhulẹ bi gbogbo ẹ ṣe maa ri.