Ẹgbẹrun lọna mọkanlelogun agbofinro ni yoo pese aabo nibi idibo gomina Ọṣun – Alkali Baba

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọga agba patapata funleeṣẹ ọlọpaa lorileede yii, Usman Alkali Baba, ti sọ pe ko si ewu loko longẹ lori ọrọ eto aabo lasiko idibo gomina ipinlẹ Ọṣun ti yoo waye nipari ọsẹ yii.

 

Nibi ipade awọn lamẹẹtọ lori ọrọ idibo yii, eleyii ti ajọ eleto idibo (INEC), ṣagbekalẹ rẹ niluu Oṣogbo lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni Alkali ti sọ pe digbi lawọn agbofinro wa lati ri i pe eto naa lọ nirọwọ-rọsẹ.

O ni ẹgbẹrun lọna mọkanlelogun agbofinro ni yoo wa kaakiri awọn wọọdu ojilelọọọdunrun un o din mẹjọ to wa kaakiri ipinlẹ Ọṣun.

Alkali ke si gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati ma ṣe kọkan soke rara lori ọrọ aabo, nitori aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia wọn, ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo.

Nibi eto naa ni Alaga ajọ eleto idibo, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, ti sọ pe ninu awọn eeyan miliọnu meji o din diẹ (1,955,657) ti wọn forukọ silẹ fun kaadi idibo, awọn miliọnu kan aabọ o din diẹ (1,463,047) ni wọn ti gba kaadi wọn.

O ke si awọn ẹẹdẹgbẹta o din diẹ to ku ti wọn ko ti i gba lati lo anfaani afikun asiko titi di Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lati ṣe bẹẹ, ki wọn le lanfaani lati dibo fun ẹni to ba wu wọn.

Bakan naa ni alakooso ajọ INEC nipinlẹ Ọṣun, Ọjọgbọn Abdulganiy Raji, sọ pe pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ti ọrọ kan ninu eto idibo yii, laarin wakati mejila lawọn yoo kede esi idibo ti yoo waye lopin ọsẹ ọhun.

O ni awọn ti gbe awọn ibudo idibo kuro ni ileejọsin, iwaju aafin ọba ati iwaju ile awọn oloṣelu lọ si awọn agbegbe to fẹ daadaa fun aabo ẹmi awọn oludibo.

Ninu ọrọ tirẹ, Ọọni Ifẹ, Ọba Ẹnitan Adeyẹye Ogunwusi, ke si awọn oloṣelu lati mọ pe ohun gbogbo teeyan ba ṣe ni yoo wa ninu iwe itan, ki wọn kiyesi gbogbo igbesẹ wọn.

Ọba Ogunwusi rọ wọn lati ma ṣe doju awọn ọdọ kọ ara wọn, ki wọn faaye gba idibo ti ko lọwọ kan eru ninu, ki wọn si jẹ ki ipinlẹ Ọṣun jẹ awokọṣe rere lori idibo lorileede Naijiria.

Leave a Reply