Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Dokita Deji Adeleke, to jẹ ẹgbọn gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti ṣeleri lati pe pariwo sita bi aburo oun ba yẹsẹ kuro ninu ijọba daadaa to ṣeleri fawọn araalu nipinlẹ naa.
Oludasilẹ yunifasiti aladaani kan ti wọn n pe ni Adeleke University, to wa niluu Ẹdẹ, lo sọrọ naa lasiko ayẹyẹ ikẹkọọgboye ileewe ọhun.
O ni aburo oun, iyẹn Ademọla Adeleke, ko ni idi pataki kan lati kuna ninu iṣejọba, tabi ja awọn araalu ti wọn dibo yan an kulẹ. O fi kun un pe oun ti gba gomina tuntun naa nimọran ko ma ṣe yan ẹnikẹni to ba jẹ pe erongba rẹ lati wa si ileejọba ni ko waa kowo jẹ.
Deji Adeleke ni Ọlọrun ba gomina tuntun yii ṣe e, ko ni baba isalẹ kankan ti yoo ko owo fun, bẹẹ ni ko ni gbese owo ipolongo lasiko idibo ti yoo da pada fun ẹnikẹni nitori gbogbo awọn owo to na lasiko ipolongo ibo jẹ eyi ti awọn ololufẹ rẹ atawọn to gbagbọ ninu rẹ, pẹlu awọn afẹnifẹre fun un. Nidii eyi, ko gbọdọ ja awọn araalu ti wọn fibo wọn gbe e wọle kulẹ, ko si gbọdọ yẹsẹ.
Dokita Adeleke fi kun ọrọ rẹ pe ko sẹni to n reti owo kankan latọdọ gomina tuntun, idile awọn runpa-runsẹ si idibo yẹn lati tu awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun silẹ lọwọ awọn ijọba buruku atawọn adari ti ko lafojusun ni.