Monisọla Saka
Mọnde, ọjọ Aje, to n bọ, ti i ṣe ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, nijọba apapọ ti kede gẹgẹ bii isinmi lẹnu iṣẹ lati fi ṣami Maulid Nabiyy to jẹ ayajọ ọjọ ibi Anabi Muhammad. Ijọba sọ eleyii di mimọ gba ti ẹnu Minisita fọrọ abẹle, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla. Nibẹ lo ti ki awọn Musulumi nile, loko ati lẹyin odi ku ewu oju wọn to tun ri ọdun yii.
Ninu atẹjade ti akọwe agba ileeṣẹ ọhun, Dokita Shuaib Belgore, buwọ lu l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, niluu Abuja, lo ti rọ awọn ọmọ orilẹ-ede yii lati ṣamulo ẹmi ifẹ, suuru, amumọra, iwa ọmọluabi to jẹ awọn iwa arikọṣe ti a ri lara Anabi nigba aye ẹ. O ni ta a ba le mu un nibaada, yoo tubọ mu ki alaafia, ifẹ ati eto aabo to gbopọn gberu si i ni ilẹ wa.
Bakan naa ni Arẹgbẹṣọla ke pe awọn ọmọ Naijiria, ni pataki ju lọ, awọn Musulumi, lati yago fun iwa ipanle, riru ofin atawọn iwa ọdaran mi-in. O ni gẹgẹ bii aṣaaju nilẹ alawọ dudu, awokọṣe rere lo yẹ ka jẹ fawọn orilẹ-ede mi-in nilẹ Afrika. Bẹẹ lo tun rọ awọn ọdọ lati tẹpa mọṣẹ, ki wọn maa fi ifẹ lo pẹlu ọmọlakeji wọn lai wo ti ẹsin, ẹya tabi ipo tiru ẹni bẹẹ wa lawujọ lati le fọwọsowọpọ pẹlu ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ninu ilakaka ẹ lati sọ ilẹ Naijiria di orilẹ-ede nla ati ohun amuyagan fawọn ọmọ Naijiria.