Ipinlẹ Ekiti ṣayẹyẹ idagbere fun Fayẹmi, o loun ti da ẹyẹ ipinlẹ naa pada

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Gomina ipinlẹ Ekiti ana, Dokita Kayọde Fayẹmi, ti ṣalaye pe oun ti ṣe oun gbogbo lati ọdun mẹrin ti oun fi wa lori aleefa gẹgẹ bii gomina lati mu ileri oun ṣẹ.

Fayẹmi sọ pe ni pataki ju lọ, oun ti da ogo ipinlẹ naa pada, ni pataki ju lọ, lati sọ ipinlẹ naa di ibi amuyangan lorilẹ ede Naijiria.

Fayemi sọ eyi lakooko ẹyẹ ikẹyin ti wọn ṣe fun un, gẹgẹ bii ọkan lara awon ayẹyẹ to fi gbe ipo fun gomina tuntun ni ipinlẹ naa, Ọgbẹni Biọdun Oyebanji.

Lakooko ayẹyẹ naa to waye ni gbagede ile ijọba ipinlẹ naa l’Ado-Ekiti, Fayemi to tun ṣe ayẹwo yiyan fanda awọn ọlọpaa, lakooko ayẹyẹ naa sọ pe oun ti sin ipinlẹ naa pẹlu gbogbo ifẹ ati ọkan oun, bo tilẹ jẹ pe aisan Korona to bẹ silẹ, lọdun meji sẹyin ko fun oun laaye lati ri owo lati pari gbogbo iṣẹ ti oun bẹrẹ.

Ayẹyẹ naa to mu ayẹwo tuntun ba ọfiisi gomina nipinlẹ Ekiti pẹlu bi gbogbo awọn ọmọ igbimọ iṣejọba gomina tẹlẹ ọhun ati awọn akọwe agba, awọn ọba ati gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba atawọn malọbi gomina tẹlẹ ọun ṣe wa nibi ayẹyẹ naa.

Fayẹmi ti wọn fi ọkọ awọn ọlọpaa gbe oun ati iyawo rẹ wa sibi ayẹyẹ naa n ṣe ojuṣe ikẹyin rẹ, o tun buwọ lu iwe kan lati tu awọn ẹlẹwọn mẹẹẹdogun silẹ lọgba ẹwọn Ado-Ekiti.

Bakan naa lo tun ko kọkọrọ ile-ijọba ati ti ọfiisi gomina silẹ fun gomina tuntun, Ọgbẹni Biọdun Oyebanji.

O dupẹ lọwọ gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ Ekiti, ni pataki ju lọ, gbogbo awọn ọba, o sọ pe oun ti ni akọsilẹ to dara laarin gbogbo awọn to ti ṣejọba nipinlẹ naa lati ori gomina ologun akọkọ ni ipinlẹ naa.

Leave a Reply