Ekiti 2022: Esi idibo awọn araalu ni yoo sọ ẹni ti wọn fẹ nipo- Ẹlẹka

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Igbakeji gomina ipinlẹ Ekiti lasiko iṣejọba Gomina Ayọdele Fayoṣe toun naa fẹẹ dupo gomina tẹlẹ ki ohun gbogbo too yipada, Oluṣọla Ẹlẹka naa ti darapọ mọ awọn oludibo ti wọn jade lati dibo lasiko ibo gomina to n lọ lọwọ nipinlẹ naa.
Ẹlẹka to dibo ni Wọọdu keji, Yuniiti keje, ni Okeruku, niluu abinibi rẹ ti i ṣe Ikẹrẹ Ekiti, sọ pe eto idibo naa lọ daadaa, o ni ko si ojooro tabi magomago kan ni agbegbe ti oun ti dibo naa.
Ọkunrin naa ni ni wọọdu oun nikan, ọlọpaa bii meje lo wa nibẹ, bẹẹ ni awọn agbofinro mi-in naa si wa kaakiri ti wọn n lọ ti wọn n bọ lati ri i pe ko si wahala kankan. O gboṣuba fun awọn ẹṣọ eleto aabo fun igbesẹ yii.
Ẹlẹka ni igbesẹ eto idibo naa lọ bo ṣe yẹ ko lọ, ati pe bi ẹnikẹni ko tiẹ sọ fun awọn oludibo, o di dandan pe wọn maa duro lati ri i pe wọn mojuto ibo ti wọn di.
Bẹẹ lo gboṣuba fun awọn oludibo fun bi wọn ṣe to lọwọọwọ, ti ohun gbogbo si lọ bo ṣe yẹ.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, ọkunrin ti fa-a-ka-ja diẹ wa laarin oun ati ọga rẹ tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe, yii ṣalaye pe oun ti ṣe ojuṣe oun gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ ati ọmọ ilu, abayọri esi idibo naa ku sọwọ awọn oludibo, o ni ifẹ ọkan wọn ni yoo ṣẹ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//eephaush.com/4/4998019
%d bloggers like this: