Ekunwo owo-oṣu ti mo ṣe ki i ṣe nitori oṣelu o-Sanwoolu

Monisọla Saka

Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, nijọba Eko bọ sita gbangba lati wẹ ara ẹ mọ lori awuyewuye to n lọ nilẹ pe ọgbọn ati polongo ibo funra ẹ ati fun ọga ẹ, iyẹn Aṣiwaju Bọla Tinubu, ki wọn le jawe olubori ninu ibo ọdun to n bọ fun ipo ti koowa wọn n du loun ṣe fi kun owo-oṣu awọn oṣiṣẹ nipinlẹ naa.

Wọn loju aye kọ lowo oṣu awọn oṣiṣẹ tijọba gomina to wa nipo, Babajide Sanwo-Olu, mu ko gbe pẹẹli si i, bẹẹ ni ki i ṣe lati fi kampeeni nitori ati le wọle ninu ibo gbogboogbo ọdun to n bọ.

Kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ naa, Ọgbẹni Gboyega Ọmọtọṣọ, sọ fawọn oniroyin niluu Ikẹja lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii pe, owo tawọn fi kun owo-oṣu jẹ ohun ti wọn lẹtọọ si, o lawọn ṣe eleyii lati fẹmi imoore han si iṣẹ takuntakun wọn, paapaa ju lọ, lasiko tọrọ aje o ṣẹnuure yii.

O ni, “Gomina Sanwo-Olu n fi akoko yii ki awọn oṣiṣẹ nipinlẹ yii pe awọn mọ riri iṣẹ ti ẹ n ṣe, bo tilẹ jẹ pe nnkan le koko lasiko yii, sibẹ ẹ o kaaarẹ ọkan, bẹẹ lẹ o jẹ ki iṣẹ ijọba falẹ, ẹ n ṣiṣẹ yin bii iṣẹ, bẹẹ lẹ n fi ẹrin pa ẹẹkẹ awọn olugbe ilu Eko ti wọn n wa si ileeṣẹ ijọba gbogbo, ẹ n da wọn lohun bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ. Ko waa si bi ẹkunwo yii ṣe le kere tabi pọ to, gomina ni iṣẹ ti wọn fẹ ko jẹ ni, wọn ro pe akoko to fawọn oṣiṣẹ lati tun goke agba si i latara owo to n wọle sinu apo wọn, wọn si ti sọ bẹẹ.

”Tẹ ẹ ba feti silẹ gbọ ohun ti gomina sọ daadaa, wọn lawọn ti pa wọn laṣẹ nileeṣẹ olori awọn oṣiṣẹ, idasilẹ ati ileeṣẹ to n ri si ọrọ owo-ìná (treasury), lati fori kori, ki wọn si wo iye awọn oṣiṣẹ ati ọna ti a o gbe gba, ọrọ pe o ri bẹẹ ko ri bẹẹ o si nilẹ mọ, nnkan to ti yanju lọrọ ẹkunwo yii”.

Ọmọtọṣọ ṣalaye siwaju si i pe gbogbo awọn iṣẹ akanṣe yooku nijọba maa yanju ki ọdun yii to pari.

“Awọn ileewe bii ọgbọn la ni nilẹ lati ṣi, bẹẹ la ni iṣẹ akanṣe ilegbee (housing) lati ṣi bakan naa, ko too di ipari ọdun ta a wa yii, bẹẹ lawọn ọkọ oju omi igbalode naa wa lara eto iṣẹ akanṣe yii.

‘‘Bakan naa la tun n ṣiṣẹ lori ọkọ oju irin igbalode tuntun alawọ buluu ti yoo maa ko ero lati Marina lọ si Mile 12, nipinlẹ Eko”.

O kadii rẹ nilẹ pe, ijọba Sanwo-Olu n ṣiṣẹ l’Ekoo, lati mọ riri iṣẹ awọn oṣiṣẹ nipinlẹ yii si ni idi pataki to fi fi kun owo-oṣu wọn.’

Ka ranti pe, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni Sanwo-Olu dun awọn oṣiṣẹ ninu, to si fi ẹkunwo ida mẹẹẹdọgbọn owo-oṣu wọn (25%) ki wọn kaabọ sinu oṣu tuntun yii. Latigba naa lawọn eeyan, paapaa ju lọ awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Eko ti n fo fayọ.

 

Leave a Reply