Aderounmu Kazeem
Gomina Babajide Sanwo-Olu, ti ṣeleri wi pe oun yoo fi aye ni gbogbo awọn ti wọn ko ba fẹ ki ipinlẹ Eko ni ilọsiwaju lara.
Lasiko ti Gomina Nasir El-Rufai, sabẹwo si i lori bi wọn ti ṣe ba ọpọlọpọ dukia jẹ lasiko rogbodiyan SARS ni Sanwo-Olu sọrọ yii. El-Rufai paapaa tiẹ ni nigba ti oun ri awọn ohun to bajẹ yii, diẹ lo ku ki oun sunkun.
Sanwo-Olu sọ pe ipinlẹ Eko ti tẹ ṣiwaju lori bi awọn ohun ti wọn bajẹ yii yoo ṣe ri atunṣe. Bẹẹ lo sọ pe ijọba oun ko ni i gba gbẹrẹ fun ẹnikẹni to ba fẹ da wahala silẹ tabi ba awọn dukia ijọba jẹ l’Ekoo.
Akọwe iroyin fun Sanwo-Olu, Ọgbẹni Gboyega Akọsile, sọ pe fọto teṣan ọlọpaa ti wọn sọna si loriṣiiriṣi atawọn dukia mi-in ti wọn bajẹ fẹẹ pa gomina ipinlẹ Kaduna lẹkun nigba to ri wọn.
Ninu ọrọ Nasir El-Rufai lo ti sọ pe omi fẹẹ bọ loju oun nigba ti oun ri i bi awọn janduku ṣe ba nnkan jẹ kaakiri ipinlẹ ọhun lasiko rogbodiyan SARS.
Gomina ipinlẹ Kaduna yii fi kun un pe, “Ko sẹni to ni ki wọn ma ṣewọde tako SARS, ṣugbọn ohun to bani-lọkan jẹ ni bi wọn ti ṣe n jo ile, ti wọn n ba nnkan jẹ. Iru owo tijọba tun maa na lori atunṣe awọn nnkan ti wọn ba jẹ yii, awọn ohun idagbsoke mi-in ni wọn iba na an le lori.”
Ninu ọrọ ẹ naa lo ti ba ileeṣẹ ọlọpaa kẹdun, atawọn eeyan ti wọn padanu awọn eeyan wọn lasiko iṣẹlẹ ọhun. O ni ijọba ko gbọdọ faaye gba irufẹ iwa ọdaran bẹẹ lawujọ mọ, nibi ti awọn eeyan yoo ti maa ba dukia ijọba jẹ kiri.