Faith Adebọla
Ẹlẹrii to kẹyin ninu ẹjọ ifipa ba ni lo pọ ti gbajugbaja onitiata ati adẹrin-in poṣonu nni, James Ọlanrewaju Omiyinka, tọpọ eeyan mọ si Baba Ijẹṣa, n jẹ lọwọ, ti ṣalaye nile-ẹjọ pe loootọ ni ọrọ ifẹ wa laarin olujẹjọ naa ati olufisun rẹ, Damilọla Adekọya, ti wọn n pe ni Princess, o ni ija lo de lorin dowe laarin wọn.
Ẹlẹrii naa, Ọgbẹni Olukayọde Ogunbanjọ, ni ẹlẹrii kẹrin ti Baba Ijẹṣa pe wa si kootu to n gbọ awọn ẹsun akanṣe ati iwa ifipabanilopọ, eyi to wa n’Ikẹja, nipinlẹ Eko, lati ro arojare lori ẹjọ rẹ, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹrin yii.
Agbẹjọro olujẹjọ, Amofin agba Dada Awoṣika, sọ pe idi tawọn fi pe ẹlẹrii naa wa ni lati fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni onibaara oun ati Princess n fẹra wọn, ati pe agbelẹrọ lawọn ẹsun ti wọn ka si onibaara oun lẹsẹ.
Nigba ti Ogunbanjọ n sọrọ ni kootu naa, o ni ọrẹ timọtimọ ni Baba Ijẹṣa jẹ soun, awọn si ti jọ n ṣere tiata papọ fun bii ọdun mẹẹẹdogun, tori adẹrin-in poṣonu loun naa, o loun ni wọn saaba maa n pe ni Pasitọ Jẹrosi ninu awọn fiimu ti Baba Ijẹṣa ṣe. “A jọ n ṣe eto lori redio ati tẹlifiṣan ni, a jọ ṣe fiimu ‘Iwaasu Ẹfẹ’ ati bẹẹ bẹẹ lọ ni.
Lọjọ kan ta a pari eto, Princess wa lara awọn to pe lori aago pe oun fẹẹ ba Baba Ijẹṣa sọrọ, o loun nifẹẹ si eto wa, oun si fẹẹ darapọ mọ wa, wọn si jọ sọrọ.
Nigba to ya, o tun pe lọjọ kan ni oṣu Kẹrin, ọdun 2015, pe oun fẹ ki Baba Ijẹṣa wa sọdọ oun, o yẹ ka lọ sode ariya kan lọjọ naa, ṣugbọn a o lọ nitori ti Princess, nigba ta a de ọdọ ẹ, a ba mama ẹ, atawọn mọlẹbi, a si ki wọn, mo ri i bi Baba Ijẹṣa ṣe n dọbalẹ fun gbogbo wọn bii ẹni wa nile ana.
“Emi kọja sinu mọto pe ka le maa tete lọ sẹnu iṣẹ ta a fi silẹ, mo si pe e lori aago pe ko jẹ ka tete pada, bo ṣe wọle sinu ọkọ ayọkẹlẹ ta a gbe wa ni mama Princess n dupẹ lọwọ ẹ, mama naa sọ fun un pe: “Jọọ, maa tọju ọmọ mi (Princess) o, mo mọ pe o lagidi diẹdiẹ, mo si mọ pe iwọ naa lo le loye ẹ daadaa, Ọlọrun aa wa pẹlu yin o”.
“Bi mama yii ṣe ki i to si ṣadura fun un ya mi lẹnu, mo beere lọwọ Baba Ijẹṣa pe ki lo n ṣẹlẹ, ṣe a waa ṣe mọ-mi-n-mọ-ẹ nibi lonii ni? O si jẹwọ fun mi lọjọ naa pe oun ati Princess ti n fẹra ni bonkẹlẹ, ṣugbọn oun o mọ pe niṣe lo maa dọgbọn fi oun han awọn famili ẹ lọjọ naa bo ṣe pe wa, o lo ba oun lojiji. O loun mọ nipa ibẹrẹ ajọṣe Baba Ijẹṣa ati Princess daadaa.
‘‘Emi gba a lamọran lọjọ yẹn pe ko ṣọra o, to ba mọ pe oun o ni i fẹ obinrin yii, ko tete dẹyin lẹyin ẹ, bii pe mo ti mọ nnkan to le ṣẹlẹ lọjọ iwaju ni,” ẹlẹrii naa lo ṣalaye bẹẹ.
Amọ, nigba ti agbẹjọro olupẹjọ dide, Ọgbẹni Yusuf Sule beere lọwọ Pasitọ Jẹrosi pe ki lo mọ nipa ẹsun biba ọmọde ṣeṣekuṣe to waye lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun to kọja (2021), iyẹn si fesi pe oun o si nibi ti ọrọ naa ti ṣẹlẹ, o ni ile oun l’Aguda, Surulere, loun wa, ki i ṣe Ojule Kẹtala, Opopona Wellbow, ni Iwaya, ti wọn ni Princess n gbe.
O ni gbogbo nnkan toun mọ nipa ajọṣe awọn mejeeji loun ti sọ yẹn.
Ni bayii ti tọtun tosi ti pari atotonu ati awijare wọn, Adajọ sun igbẹjọ to kan si ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ọjọ naa lawọn lọọya olupẹjọ ati olujẹjọ yoo tọwọ bọwe akọsilẹ atotonu wọn, lẹyin eyi ladajọ yoo gbe idajọ rẹ kalẹ, tabi ko sọ ọjọ mi-in ti idajọ yoo waye.
Tẹ o ba gbagbe, lati ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun to kọja ni Baba Ijẹṣa ti n paara ile-ẹjọ naa lori ẹsun mẹfa ti wọn fi kan an, pe o fipa ba ọmọọdun mẹrinla kan laṣepọ nigba tọmọ naa wa lọmọọdun meje pere, ati lọmọọdun mẹrinla, pẹlu awọn ẹsun mi-in.
Oṣu meji lo fi wa lahaamọ ọlọpaa lori ẹsun naa, ki kootu too fun un ni beeli.
Ẹlẹrii mẹfa ọtọọtọ ni olupẹjọ pe lati jẹrii ta ko Baba Ijẹṣa. Princess, ọmọọdun mẹrinla ọhun, ati dokita to ṣayẹwo wa lara awọn ẹlẹrii naa.