Kayeefi, aara san pa awọn ọdọ marun-un l’Agọọ Dada, Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Titi di asiko yii niroyin iku awọn ọdọ marun-un ti aara san pa lojiji nitosi Akurẹ, si n ṣe awọn eeyan ni kayeefi.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, iṣẹlẹ yii waye lasiko tawọn ọdọ ọhun ko ara wọn jọ sinu abule kan ti wọn n pe ni Agọ Dada, Ala, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, lati gba bọọlu afẹsẹgba nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Oku awọn eeyan ọhun ni wọn lo wa nilẹ fun ọpọ wakati, ti ko si sẹni to laya lati sun mọ wọn titi tawọn onisango fi de lati ṣetutu to yẹ ki wọn too le palẹ oku wọn mọ fun sisin.
Ẹlomi-in to tun ba wa sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun jẹ ko di mimọ pe eeyan mẹrin ni aara kọkọ san pa, nigba ti ẹni karun-un ku lasiko tawọn eeyan abule naa n fẹhonu han.
Ọkunrin to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ọhun ni iru iṣẹlẹ bẹẹ ko ṣẹṣẹ maa waye l’Agọ Dada pẹlu bo ṣe jẹ pe eeyan bii mẹsan-an ni wọn ku iru iku kan naa lọdun to kọja.

O ni eyi lo bi awọn ọdọ kan ninu ti wọn fi fẹhonu ta ko baalẹ abule naa, ẹni ti wọn gbagbọ pe ọwọ rẹ ko mọ ninu ajalu to n fi igba gbogbo waye lagbegbe ọhun.
O ni awọn ọlọpaa to tete de si asiko lo ko baalẹ yọ lọjọ naa nitori pe ṣe lawọn tinu n bi ọhun fẹẹ dana sun un ki Ọlọrun too ko o yọ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmi Ọdunlami, ni awọn mẹrin pere loun gbọ pe aara san pa.
Ọdunlami ni oun ko ri i gbọ rara pe awọn eeyan kan fẹhonu han lori iṣẹlẹ ọhun ati pe o ṣee ṣe ki ariyanjiyan waye lati ọdọ ẹbi awọn oloogbe lori ọna ti wọn fẹẹ gba sin oku wọn.

Leave a Reply