Awọn ọlọpaa ti mu Musa o, iya ẹni ọdun marundinlọgọrin lo fipa ba lo pọ titi tiyẹn fi ku mọ ọn labẹ

Ile-ejọ ni ọmọkunrin kan, Iliya Musa ti ko ju ẹni ọdun mejilelọgbọn lọ, to lọọ fipa ba iya ẹni ọdun marundinlọgọrin lo pọ tiyẹn fi ku mọ ọn labẹ nipinlẹ Adamawa, yoo ti rojọ ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ lori iṣẹlẹ naa.
Ohun ti awa ri gbọ ni pe ipinlẹ Adamawa, nilẹ Hausa lọhun-un, niṣẹlẹ kayeefi yii ti ṣẹlẹ lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ta a ṣẹṣẹ lo tan yii, ni adugbo kan ti wọn n pe ni Maduguva.
Jẹẹjẹẹ ni wọn ni iya agba yii wa ninu ile rẹ ti ọmọkunrin ẹlẹmi-in eṣu yii fi wọle tọ iya oniyaa lọ, o jọ pe ara rẹ ti kun, ko si ri ibomi-in to ti le tura ju ọdọ iya ẹni ọdun marundinlọgọrin yii lọ. Ohun to wu Musa lara iya arugbo yii to fi mu un gun bii ewurẹ ni ẹnikẹni ko ti i le sọ.
Ọmọ iya arugbo naa sọrọ pẹlu ẹdun ọkan o, o ni ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ni iṣẹlẹ naa waye. O jọ pe ọkunrin naa ko si nile gẹgẹ bii alaye to ṣe. O ni ọkan ninu awọn araadugbo awọn lo gbọ igbe buruku ti mama oun n ke ninu ile nigba ti ọmọkunrin yin n fi ‘kinni’ buruku abẹ rẹ faya iya oniyaa to jẹ Ọlọrun nikan lo mọ ọdun ti ọkunrin ti sun mọ ọn gbẹyin. Ọmọkunrin yii ni Esther Thomas lo gbọ igbe mama, lo ba ni ki oun yọju si iya naa lati mọ ohun to n mu wọn pariwo kikankikan bẹẹ.
Niṣe lo sare pada pe koju ma ribi, gbogbo ara loogun rẹ, nigba to ri Musa to n laagun yọbọ bii ẹran sunsun lori iya oniyaa bii pe ọmọ kekekre lo n gbo mọlẹ. Ọmọ iya yii to n jẹ Yohanna Adamu lo sare lọọ pe, niyẹn naa ba wọle lọọ ba Musa lori iya ẹ. Iya yii ko le mi daadaa mọ gẹgẹ bii ohun ti a ri gbọ, nigba ti wọn yoo si fi mọ ohun to n ṣẹlẹ, ‘kinni Musda ti ran iya agba yii lọ sọrun apapandodo.
Ṣugbọn Musa na jẹwọ o, o jẹwọ fun akọroyin SharaReporter kan nigba tiyẹn n fi ọrọ po o nifun pọ pe bi asẹwo ṣe kun ilu to, ti aọn ọmọ ẹlẹlẹ wa kaakiri igboro ti ko si ni i na an ni owo pupọ lati ja nnkan jẹ. O ni iṣẹ eṣu ni. Musa ni ode ariya kan loun ti n bọ jẹẹjẹ ki esu too bẹ oun wo, lo ba ni ki oun lọ taara sọdọ iya arugbo to wa ninu ile ẹ jẹẹjẹẹ nigba ti oun n gbọ ariwo iya naa lati ita. O ni boun ṣe wọle bayii, oun ko mọgba ti oun ba ara oun lori iya yii, boun ṣe gori ẹ bayii loun ba n faya iya yii tagbara tagbara. Gbogbo ariwo ti iya arugbo yii n pa ko si ba oun nile, afigba toun da tara oun si iya yii labẹ loju oun too walẹ.
O ni ọti buruku toun mu lode iyawo lo ko ba oun.
Ṣugbọn Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Sulaiman Ngoruje naa ti sọrọ o, o ni awọn ti mu Musa to n ba irọ iya to bi mama rẹ lo pọ. Awọn yoo si foju rẹ ba ile-ẹjọ laipẹ rara, nibi ti yoo ti ṣalaye ohun to fa a to fi ki iya ẹni ọdun marundinlọgọrin mọlẹ, to si ṣe ‘kinni’ fun un karakara.

Leave a Reply