Emi naa ti gba bẹẹ: Oriire ki i jinna sẹni to ba n ṣe rere

Ki eeyan ṣaa maa ṣe suuru, ko si gbọkan le Oluwa Ọba. Ko si asiko ti Ọlọrun ko le ṣe oore rẹ, ko si rara. Ohun to ṣẹlẹ si mi lọsẹ to kọja yii, ti eeyan ba sọ pe iru rẹ le ṣẹlẹ lasiko yii, n oo pe ki onifa bẹẹ ko o danu ni. Koda, bi wọn sọ fun mi pe o le ṣelẹ si ẹnikan, n oo ni tọhun n tan ara ẹ jẹ ni. Ṣugbọn o ṣẹlẹ si mi, mo si ri oore Ọlọrun. Afi ki Ọlọrun fi iru oore bẹẹ kari wa. Ati pe ọmọ ti wọn n pe ni Safu yii, oloriire ọmọ gbaa ni o. Ẹsẹ ẹ ti daa ju. Ṣe ẹ mọ pe mo ti n sọ ọ tipẹ, bi mo ba ri oloriire, n oo mọ pe oloriire ni.

Nitori ija ti wọn ja nile ti mo fẹẹ ba a sọrọ ni mo ṣe tete de ṣọọbu. Pẹlu bi mo ṣe tete debẹ to naa, mo ba a ni, n o ro pe o duro jẹun mọ, lẹyin tọrọ to waye yẹn ti waye, o gba ṣọọbu lọ ni tiẹ ni. Bẹẹ nigba ti mo n lọ, mo ṣi n gbọ wuruwuru Alaaji lọdọ Aunti Sikira, yoo ti fi ti eyi to ṣẹlẹ laaarọ kẹwọ, yoo ni afi ki iyẹn mu un foun. Baba naa ti ko si mọ igba kan leeyan ki i dana alẹ, yoo ti mu nnkan ẹ fun un, wọn yoo jọ maa rẹrin-in ṣinkin-sinkin, ija pari niyẹn. Ki wọn ma fi tiwọn ko ba ọmọ fun mi ni mo ṣe fẹẹ bayẹn sọrọ, nitori ẹ ni mo ṣe tete lọ si ṣọọbu!

Ko kuku tiẹ jẹ ki n sọrọ to fi kunlẹ, to ni ki n ma binu, iya oun lo da’nu bi oun, to fọ oun leti, pe oun ko le ranti igba ti ẹnikẹni ti fọ oun leti gbẹyin, ohun to jẹ ki oun da tiẹ pada fun un niyẹn. Mo ni ṣe o mọ pe agbalagba ni, aunti lemi gan-an n pe e, oun lo si wa nipo ti Alaaji to oun Safu si bayii, obinrin o si le ṣe ko ma jowu iru ẹ, pe to ba ti di ọjọ mi-in ti ọrọ ba fẹẹ le bẹẹ, ko tete yipada kuro nibẹ, ko gba ọna tirẹ lọ, ko ma jẹ ki ẹni kan ba tiẹ jẹ, ko ma jẹ ki ẹni kan fi eegun ba oun lẹran jẹ, ki wọn ma si sọ ọ lẹnu nile ati laduugbo pe oniwahala ni.

Iyẹn la n sọ lọwọ o, bi Aunti Jẹmila ṣe waa pe mi niyẹn. Aunti Jẹmila ni lanledi mi. Oun lo ni ṣọọbu meji ninu mẹta ti a n lo. Ọwọ ẹ ni mo ti kọkọ gba ẹyọ kan, igba to ya lo di meji, oun naa lo si ṣe ọna ti aburo wọn ti wọn fun ni ṣọọbu kẹta ṣe gbe e fun mi, oun naa lo n ba a gbowo ẹ. Ile ilẹ nile naa, wọn kan to ṣọọbu siwaju ẹ ni. IIẹ lemi ti gba, ti mo ja meji pọ, ti mo tun waa gba kekere to wa lẹgbẹẹ, ti mo yọ ọfiisi sibẹ. Ṣugbọn gbogbo igba ni ariwo maa n ṣẹlẹ nile naa laarin awọn ọmọ baba to ni in, baba to ti ku lati bii aadọta ọdun sẹyin.

Awọn ọmọ bii mejila ni wọn si wa lori ile kan ṣoṣo naa, gbogbo yara to si wa nibẹ ati bọsikọta ko ju mẹrinla lọ. Emi o ki i ba wọn da si ija wọn o, Ọlọrun si ṣe e, awọn naa ki i ko ẹjọ wọn waa ba mi, gbogbo wọn ni wọn maa n fun mi lọwọ nibẹ, emi naa ko si jẹ kọja aaye mi. Aunti Jẹmila lẹgbọn wọn, ṣugbọn o ti wa nile baba wọn yẹn ti mo ti mọ ọn, o ti le lọdun mẹẹẹdọgbọn, o ti ba ọkọ ẹ ja, ko si pada lọ sibi kan, owo ṣọọbu ẹ lo fi n jẹun, to si tun n gbe yara kan ninu ile nibẹ, bi wọn ṣe pin in ko ye mi. Ṣugbọn o fẹran mi gan-an nitori ko si igba to tọrọ nnkan lọwọ mi ti n ko ni i fun un, bo ba si ni ki n ya oun lowo kan, mo maa fun un ni, n o jẹ ya a lowo.

Mo ro pe gbogbo oore yii lo ro papọ, lo fi sare waa ba mi laaarọ yẹn. Ni mo ba tẹle e lọ si yara ẹ, mo tiẹ kọkọ ro pe o fẹẹ yawo ni, mo ṣaa ti mọ pe eyi o wu ko jẹ, apa Ọlọrun aa ka a. N lo ba sọ fun mi pe awọn aburo oun ati gbogbo awọn iya awọn ti gba pe awọn fẹẹ ta ile yii ni kiakia, pe laarin oṣu kan yii ni wọn fẹẹ ta a. Wọn ni awọn ọmọ yẹn sọ pe iya n jẹ awọn, pe ti awọn ba ta ile naa, awọn aa lọọ ra ilẹ si Ọna Mowe, awọn aa kọ ojule mejila bayii sibẹ, tabi ju bẹẹ lọ, awọn aa le ri owo pin laarin ara awọn, nitori ile Oṣodi ṣaa maa gbowo lori.

Mo ni eelo ni wọn fẹẹ ta a, o ni wọn ni ọgọfa miliọnu jalẹ ni. Niṣe nidi mi domi. O loun o fẹ ki ẹlomi-in ra a loun ṣe waa ba mi, ki n wa a ni gbogbo ọna, ki n ra a. Mo ni mo ti gbọ, pe o ṣeun, mo ni bi ọrọ ba ṣe jẹ, n o wa a ri i lọjọ keji. Mo ti mọ pe n ko ni esi kan ti mo fẹẹ fun un. N oo ra a. Mo mọ pe bi mo ba ṣa ile jọ, ti mo ṣa ọna jọ, bi owo naa o ba pe, n oo ri ya si i lọdọ banki mi, wọn ṣaa ti n bẹ mi ki n wa yawo lọdọ wọn tẹlẹ, mo si lawọn iwe ile ti mo le fi duro. Ṣugbọn n ko fẹ ko wahala kan sọrun mi, ki oluwa-ẹ maa waa sa jan-an jan-an kaakiri.

Bo ba jẹ Sẹki wa nitosi ni, emi pẹlu wọn la ba jọ fi wọn ṣe yẹyẹ daadaa, ṣugbọn wahala tiyaale ẹ yẹn ti fẹrẹ sọ oun naa di olokun-unrun, nitori ko si ọjọ naa ti ki i lọọ ri Iya Tọmiwa ni ibi to wa. O tiẹ lo ti n fi igi rin daadaa bayii, ọkọ ẹ naa si ti jade sita lẹyin ti wọn ti ṣi ọna, wọn jọ maa n lọọ wo o ni. Aisi nile Sẹki ko jẹ ki yẹyẹ ti mo fẹẹ ṣe dun-un ṣe. Ṣugbọn igba ti Safu beere lọwọ mi, mo ni ko ma da wọn lohun, ẹni ti wọn fẹẹ da laamu ni wọn n wa. Lo ba ni ki lo de, ni mo ba ṣalaye fun un. Oju to fi wo ọrọ naa, ọtọ patapata gbaa ni.

O ni gẹgẹ bii iroyin ti mo ṣe foun nipa ara mi ati ṣọọbu yii, ṣe emi ko mọ pe ibẹ ni Ọlọrun ti gbe gbogbo oriire mi ba mi ni. Pe ile daadaa to ba irawọ mi mu ni, eeyan ki i si i kuro ni iru ibẹ bi ko ba jẹ ohun ti ko dara ba ṣẹlẹ si i. O ni tabi n ko mọ pe bi wọn ba ta a fẹlomi-in bayii, wọn yoo le wa kuro nibẹ, agaga bo ba jẹ awọn ti wọn fẹẹ kọ nnkan mi-in sori ilẹ naa ni. Pe ti wọn ba le wa, ti a ba ko lọ sibomi-in, a le ma ri taje ṣe to ibi ti a wa ti gbogbo aye ti mọ mi mọ yii. Niṣe ni mo mi kanlẹ, mo ni n ko ronu lọ sibi to ronu lọ yii rara. Ṣugbọn iṣoro wa.

Safu ni iṣoro kin ni. Mo ni n ko lowo to to bẹẹ yẹn lọwọ. Lo ba n rẹrin-in, o ni iyẹn kọ niṣoro, pe iṣoro ibẹ ni ki n kọkọ gba lọkan ara mi pe mo fẹẹ ra a, o ni ti mo ba ti gba bẹẹ, mo maa ra ile naa, pe temi ni, Ọlọrun maa ṣe ọna fun mi nidii ẹ. Ni mo ba ni, “O daa o, mo ti gba o, mo maa ra a o, tiwa ni o!” Ni Safu ba bẹrẹ si i jo o, ijo gidi, lo n kọrin asalaatu pe “Ọlọrun to ṣeyi a dupẹ, Ọlọrun to ṣeyi o ṣeun …” Ṣe ẹyin naa ri i pe nnkan ni ọmo Safu ti Alaaji gbe wale yii loootọ!

Leave a Reply