Emi ni mo ge ọwọ ati ẹsẹ Mesesi, nitori mi o ba owo pupọ lapo rẹ-Dauda

Gbenga Amos, Abẹokuta

 Iya agbalagba ẹni ọdun mọkanlelaaadọrin (71) kan, Abilekọ Mesesi Adisa, ti ri iku ojiji he, ki i ṣe iku ojiji lasan, iku gbigbona ni, Ọgbẹni Dauda Bello, ẹni ọdun mẹrinlaaadọta (51) lo fọ’gi mọ iya naa lori, bi obinrin naa ṣe n japoro iku lọwọ lo ba gbe e lọ sinu oko, o pa a, o si rẹ ọrun ọwọ ati ọrun ẹsẹ rẹ lọ.

Iṣẹlẹ yii waye niluu Imala, nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta, ipinlẹ Ogun. Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe fidi rẹ mulẹ, o sọ pe ọjọ keje, oṣu Keje ta a wa yii, lọwọ ba afurasi apaayan yii.

O ni lati ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ni oloogbe naa ti jade nile rẹ, bii ẹni pe o kan fẹẹ gbatẹgun laduugbo, ṣugbọn alọ ni wọn ri, wọn o ri abọ rẹ mọ, lo ba dẹni awati.

Nigba tawọn mọlẹbi ati ojulumọ wa mama naa titi, ti ko sẹni to foju kan an, ni wọn ba lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa to wa lagbegbe Sabo si Ilupeju, lawọn ọlọpaa ba bẹrẹ iṣẹ iwadii ati ifimufinlẹ to lọọrin ni ẹka to n gbogun ti iwa ijinigbe, tori wọn kọkọ ro pe niṣe ni wọn ji mama arugbo naa gbe lọ ni.

Bi wọn ṣe n ṣewadii, wọn tọpasẹ mama naa de ibi ti wọn ti ri i gbẹyin, eyi lo gbe wọn de ọdọ Dauda, tori ọdọ rẹ, ni ile rẹ to wa laduugo Olodo, niluu Imala, ni itọpinpin fihan pe mama naa de kẹyin to fi dawati.

Ọjọ keje, oṣu Keje yii, ni SP Taiwo Ọpadiran, atawọn ẹmẹwa ẹ lọọ fi pampẹ ofin gbe Dauda, wọn si wọ ọ lọ sakata awọn ọtẹlẹmuyẹ, l’Abẹokuta, lati ṣalaye ohun to mọ nipa bi mama onimama ṣe poora bii iso.

Ṣugbọn bi baba ẹni ọran yii ṣe de tọlọpaa lo ti jẹwọ fun wọn pe loootọ loun ri ẹni ti wọn n wa naa, o ni alajọṣe okoowo kan naa pẹlu oun ni, awọn jọ n ṣe okoowo fifi ọmọ ṣẹru sẹyin odi ni, awọn si ti n ba ara awọn bọ, ọjọ ti pẹ, ati pe oun mọ nipa bo ṣe dawati.

O jẹwọ pe oun loun ranṣẹ pe e lọjọ iṣẹlẹ ọhun, tori kawọn si le jọ jiroro nipa bisinẹẹsi tawọn jọ n ṣe loun ṣe ranṣẹ si i. Ṣugbọn nigba to de ọdọ oun, oun fura pe owo nla kan wa lọwọ ẹ, tori igbanu ẹ wu, eyi lo mu koun dọgbọn buruku kan, oun gba ọna ẹyin fọ’gi mọ ọn lori lojiji, lo ba ṣubu.

O loun gbe e nigba to n pọkaka iku lọwọ, o di inu igbo, ibẹ loun ti gbẹmi lẹnu ẹ. Nigba to ku tan loun yẹ ara ẹ wo pẹlu ireti lati ko owo rẹpẹtẹ, ṣugbọn o ya oun lẹnu pe ẹgbẹrun mejilelogun ati igba Naira pere (N22,200) lo wa ninu igbanu to san mọ’dii, o si ṣe oun laaanu pe oun ti pa a tan koun too mọ pe owo tabua kọ lo wa nibẹ, ṣugbọn ẹmi ẹ ko ṣee da pada foun mọ.

Afurasi ọdaran yii tun jẹwọ pe oun ge ọrun ọwọ ati ẹsẹ oloogbe naa, o niṣe loun ta a fun awọn ti wọn nilo ẹ, oun si sin iyoku ara oku naa sinu igbo.

Alukoro ọlọpaa ni ọkunrin naa ti mu awọn ọtẹlẹmuyẹ lọọ sibi to ti dabira buruku yii, wọn si ba oku oloogbe naa nibi to sin in si, o ti n jẹra, ṣugbọn wọn hu jade, wọn si ti gbe e lọ si mọṣuari.

Bakan naa ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti paṣẹ pe kawọn ọtẹlẹmuyẹ tete pari iṣẹ iwadii wọn, tori afurasi yii gbọdọ kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ laipẹ, gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply