Emi ni mo ni iriri ju ninu gbogbo awọn oludije sipo aarẹ-Ọṣinbajọ

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ni aafin Ewi Ado-Ekiti, Ọba Rufus Adeyẹmọ Adejugbe, ni Igbakeji Aarẹ orilẹ-ede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajọ, ti sọ pe oun loun kun oju oṣuwọn ju, oun ni imọ, oun si tun ni iriri ju lati gba ipo lọwọ Ọgagun Mohammadu Buhari ninu gbogbo awọn oludije ninu eto idibo ọdun to n bọ.
Ọṣinbajọ sọrọ yii l’Ọjọbọ, Tọsidee, lakooko abẹwo to ṣe sawọn ọmọ ẹgbẹ Onigbaalẹ nipinlẹ Ekiti lati beere fun atilẹyin wọn lakooko eto idibo abẹle ẹgbẹ naa to n bọ lọna.
Ọṣinbajọ juwe ara rẹ gẹgẹ bii ọlọgbọn ati oloye, to si ni imọ pupọ nipa eto ati bi ọjọ iwaju Naijiria yoo ṣe dara. O ni ti oun ba wọle gẹgẹ bii aarẹ, oun yoo wa atunṣe si iṣoro to n dojukọ orilẹ-ede Naijiria, ni pataki ju lọ, eto aabo ati ọrọ aje to dẹnu kọlẹ.
O ṣalaye pe didije ti oun fẹẹ dije wa lati ṣiṣẹ sin awọn ọmọ orilẹ-ede yii ni. O fi kun un pe iriri ti oun ti ni gẹgẹ bii Igbakeji Aarẹ ati lakooko ti oun ṣe adele fun Aarẹ ti fi oju oun si awọn anfaani to wa lorilẹ-ede yii.
O ni oun ti ṣetan lati tun orile-ede yii sọ bii ẹni sọ igba, ki idagbasoke le ba awọn ọmọ Naijiria.
O juwe Aarẹ Buhari to ti ṣiṣẹ labẹ rẹ fun ọdun meje gẹgẹ bii oloootọ ati oniwa tutu eniyan. O ni iriri ati ẹkọ ti oun ri labẹ Buhari lo mu oun jade lati dupo aarẹ naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ” Mo fẹẹ sọ fun yin pe didije ti mo n dije fun ipo aarẹ fi han pe Ọlọrun Ọba ti fun mi ni anfaani lati fi ara mi silẹ lati sin orilẹ-ede mi. Lati ọdun meje ti mo ti wa lori ipo gẹgẹ bii Igbakeji Aarẹ, mo ti ṣoju Aarẹ lọpọlọpọ igba, bakan naa ni mo ti ni anfaani lati wa nidii eto iṣejọba ati bi alaafia yoo ṣe de ba orilẹ-ede yii ni gbogbo ẹka.
“Mo ti ni anfaani lati ṣiṣẹ labẹ Aarẹ to loye, to si ni erongba bi orilẹ-ede yii yoo ṣe dara, bẹẹ lo tun fun mi ni anfaani lati jẹ ki n mọ awọn iṣoro to n doju kọ orilẹ-ede Naijiria ati awọn orilẹ-ede miiran.

” Mo layọ lati sọ fun yin pe mo ti ni anfaani ati iriri pupọ, eyi to fi ọkan mi balẹ lati dije fun ipo aarẹ. Mo fẹ ki ẹ mọ pe ti mo ba kọ ti n ko jade lati dije pẹlu gbogbo ẹkọ ti mo ti kọ labẹ Aarẹ Muhammadu Buhari, yoo jẹ ohun itiju fun mi ati awọn alatilẹyin mi.
” Mo si n fi akoko yii sọ fun yin pe ninu gbogbo awọn oludije to fẹẹ dije dupo aarẹ, emi ni mo ni oye ati ọgbọn ju lati ṣiṣẹ yii, idi niyi ti mo fi wa sibi lati ba awọn ọmọ ẹgbẹ ati awọn aṣoju ẹgbẹ Onigbaalẹ sọrọ pe ki wọn dibo fun mi lakooko idibo abẹle wa to n bọ lọna. Ki Ọlọrun ran mi lọwọ, ko si da ẹmi gbogbo ọmọ ipinlẹ Ekiti si lati jẹ ere iṣejọba mi ti mo ba de ori ipo.”
Ọjọgbọn Ọṣinbajọ tun gbe oṣuba kare fun Ewi ti Ado-Ekiti, Ọba Rufus Adejugbe, pẹlu bo ṣe jẹ ki alaafia ati idagbasoke jọba ni ilu naa.
Ọba Adejugbe juwe Igbakeji Aarẹ gẹgẹ bii ẹni to kun oju oṣuwọn lati ṣejọba orilẹ-ede Naijiria. O tun dupẹ lọwọ rẹ fun akitiyan rẹ lati ri si idagbasoke orilẹ-ede Naijiria, o waa gbadura fun Igbakeji Aarẹ pe yoo yege ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ Onigbaalẹ, o si ran an leti pe ko ma ṣe gbagbe igbaye-gbadun awọn ọba to ba wọle.

Leave a Reply