Ọlawale Ajao, Ibadan
Inu ọfọ ati airoju ni gbogbo mọlẹbi kan torukọ idile wọn n jẹ Adeagbo, niluu Tede, nijọba ibilẹ Atisbo, nipinlẹ Ọyọ, wa bayii pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe gbe iya ati ọkan ninu awọn ọmọ wọn ju satimọle lẹyin ọjọ bii meji ti olori ẹbi naa, Ọgbẹni Jimoh Adeagbo, jade laye.
Ki i ṣe pe baba agbẹ ti wọn n pe ni Jimoh Adeagbo yii fọwọ rọri ku, ọmọ bibi inu ẹ, Ismail Adeagbo, lo lu u pa lọjọ ọdun Itunu Aawẹ to kọja yii, gẹgẹ bi SP Adewale Ọṣifẹṣọ ti i ṣe Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ṣe fìdi ẹ mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan.
SP Ọṣifẹṣọ ṣalaye pe “Ni nnkan bii aago mọkanla alẹ ọjọ Jimọ, ọjọ kọkankanlelogun (21), oṣu Kẹrin, ọdun 2023 yii, lọjọ ọdun Itunu Aawẹ, nigba ti Ọgbẹni Adeagbo n sun lọwọ ninu ile ẹ to wa laduugbo Somọ́lá, niluu Tede, lọkan ninu awọn ọmọ ẹ to n jẹ Ismail la irin mọ ọn lori, ti baba naa si gbabẹ lọ sọrun alakeji.
“Ismail funra rẹ naa lo lọọ tufọ fun ọmọ ẹgbọn baba ẹ to n jẹ Taofeek Adeagbo, pe baba oun ti ku. Ṣugbọn ko jẹwọ pe oun loun pa a, o ni nigba ti oun ji laaarọ ọjọ naa loun ba oku baba oun lori ibusun pẹlu oju ọgbẹ kan niwaju ori ẹ.
“Iwadii ta a ṣe lo fidi ẹ mulẹ pe Ismail gan-an lẹni naa to la irin mọ baba ẹ lori titi ti onitọhun fi tọju oorun doju iku.
“Oun naa ti fẹnu ara ẹ jẹwọ fun wa pe oun loun la irin mọ baba oun lori to fi ku. O ni iya oun naa mọ pe oun loun pa baba oun, o kan pinnu lati bo oun laṣiiri ni.
“Nitori pe iya yẹn mọ nipa iṣẹlẹ yẹn, ṣugbọn to kọ lati tu aṣiri iwa ọdaran yii sita la ṣe mu oun naa, nitori o lodi sofin fun ẹnikẹni lati mọ nipa iwa ọdaran kan, ki oluwarẹ si dakẹ lai fi iru iṣẹlẹ bẹẹ to awọn agbofinro leti”.
Ismail, ẹni ti ko ju ọmọọdun mejidinlogun (18), lọ funra rẹ fìdi ẹ mulẹ, o ni ki i ṣe pe baba oun ṣẹ oun lẹṣẹ kan, ẹmi kan lo kan dari oun pe ki oun lọọ la irin mọ baba oun lori lai ṣe pe ija wa laarin awọn ti tẹlẹ.
Gẹgẹ bi ọmọkunrin to n lọ sileewe girama Progressives Secondary School, niluu Tede naa ṣe sọ, “emi funra mi gan-an ko mọ nnkan to kọ lu mi, mo kan deede ji laarin oru yẹn lẹmi yẹn sọ fun mi pe ki n lọọ la irin mọ baba mi lori. Bi mo ṣe dide lọọ ba wọn niyẹn, ti mo si la irin mọ wọn lori lori bẹẹdi ti wọn sun si”.
Ẹgbọn Ismail kan to n jẹ Taofeek Adeagbo ni wọn lo lọọ fiṣẹlẹ ọhun to awọn agbofinro leti ti wọn fi mu Iya Ismail, Abilekọ Rasheedat Adeagbo, wọn lo mọ si iṣẹlẹ ipaniyan naa, o si kọ lati sọ ọ fawọn ki awọn le gbe igbesẹ to ba yẹ le e lori labẹ ofin.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, iyawo oloogbe naa, Abilekọ Rasheedat Adeagbo, ṣalaye pe oun ko lọwọ ninu iku ọkọ oun, oun naa kan ji nidaaji ọjọ naa loun ri i pe ọkunrin naa ti ku sori bẹẹdi to sun si.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Bi mo ṣe ji laaarọ ọjọ yẹn, mo ji gbogbo awọn ọmọ mi lati lọọ kirun asubaa gẹgẹ bi mo ṣe maa n ṣe lojoojumọ, afi bi mo ṣe de yara ọkọ mi ti mo ba oku ẹ lori bẹẹdi. Mo pariwo, awọn araadugbo sare de. Taofeek lọọ tufọ fawọn ẹbi.
“Loootọ ni mo mọ pe ọwọ ọmọ mi ni iku baba ẹ ti wa, ṣugbọn emi o lọwọ nipa iku ọkọ mi. A maa n ja lẹẹkọọkan loootọ, ṣugbọn ta a ba n ja, bii ka ku kọ. Ọmọ meje ni mo kuku bi fun un, mi o jẹ ro ibi ro o laelae.
“Awọn famili ẹ naa ni wọn lọọ fẹjọ sun awọn ọlọpaa. Nigba tawọn ọlọpaa de, wọn beere awọn ọmọ oloogbe, gbogbo wọn jade si wọn, ṣugbọn Ismail sa pamọ sabẹ bẹẹdi. Lẹyin ti awọn ọlọpaa lọ tan ni mo bi i leere pe ṣo mọ nipa iku baba ẹ ni, o si jẹwọ fun mi pe oun loun la irin mọ ọn lori”.
Iwadii awọn agbofinro ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii gẹgẹ bi SP Ọṣifẹṣọ ṣe fidi ẹ múlẹ.