Faith Adebọla
Yoruba bọ, wọn ni ẹni ti ọrẹ da ko ma binu, ẹni abinibi n da’ni. Ọrọ yii ṣe wẹku pẹlu bi afurasi ọdaran ẹni ọdun mẹrindinlogoji tọwọ awọn agbofinro ṣẹṣẹ ba kan, Ọgbẹni Halilu Abubakar, ṣe jẹwọ pe nitori ki oun ma baa san gbese owo kẹkẹ Maruwa toun jẹ ọmọ aburo baba oun, Abilekọ Binta Abusafyan, loun ṣe tan an lọ sọdọ awọn ajinigbe, pe ki wọn ji i gbe, ki wọn gba owo lọwọ rẹ daadaa, ki wọn si pa a sọnu.
Ṣugbọn riro ni teniyan, ọna iyanu gbaa l’Ọlọrun gba doola ẹmi obinrin ọhun, to fi bọ lọwọ awọn ajinigbe, to si lọọ fẹnu ara rẹ ṣalaye ohun toju rẹ ri lakata wọn, lẹyin tawọn ajinigbe mọkanla ti ṣeku pa ara wọn nitori ọmọbinrin naa tan.
Ninu igbo kijikiji kan tawọn ajinigbe ti sọ di ibuba wọn, nitosi ilu Galadimawa, nijọba ibilẹ Giwa, nipinlẹ Kadunan niṣẹlẹ yii ti waye.
Ninu alaye tobinrin naa ṣe fawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ikọ Intelligence Response Team (IRT) to wa ni Ragachigun, niluu Kaduna, obinrin naa sọ pe oun ati afurasi ọdaran yii lawọn jọ n lọ sibi kan to loun ti fẹẹ lọọ gba owo toun maa fi san balansi owo to jẹ oun pada, lawọn ajinigbe naa ba yọ si awọn lojiji, ti wọn si ji awọn mejeeji gbe.
Lẹyin ọjọ marun-un ninu igbo naa, o loun ri aaye sa mọ wọn lọwọ, loun ba bẹrẹ si i wa ọna lati jade, ṣugbọn ọna ti daru mọ oun loju tori igbo kijikiji ni, oun o mọ ọna toun le tọ bọ si gbangba, nibi toun ti n tarara kaakiri ninu igbo naa loun ti lọọ bọ sọwọ ikọ ajinigbe mi-in, lawọn yẹn ba tun mu oun lọ.
Obinrin naa sọ pe nibi ti wọn ti n mu oun lọ lawọn ti pade awọn ti wọn ti kọkọ ji oun gbe lakọọkọ, toun sa mọ lọwọ, ni wọn ba sọ fawọn ti wọn ṣẹṣẹ mu oun pe ẹran-ọdẹ awọn loun, pe ọdọ awọn ni mo ti sa kuro, ki wọn fa mi le awọn lọwọ.
O lawọn ajinigbe keji yari pe ko sohun to jọ ọ, awọn o le fa mi le wọn lọwọ, tori awọn lawọn pade mi nigba ti mo n sa lọ, ibi ti wọn ti maa ri nẹtiwọọku lati pe awọn mọlẹbi mi ki awọn si sọ iye owo ti wọn fẹẹ gba lawọn n mu mi lọ ti wọn fi pade awọn yii, tori naa, awọn lawọn maa gba owo itusilẹ lori mi.
Ọrọ yii di awuyewuye, ti awọn ajinigbe naa si da ede wọn ati ibinu buruku bolẹ, ni wọn ba bẹrẹ si i yinbọn fun ara wọn, oku sun bẹẹrẹbẹ, wọn pa mejila lara wọn ninu ẹgbẹ ajinigbe kin-in-ni ati ekeji, gẹgẹ bo ṣe ṣalaye.
Binta loun o mọ bi Ọlọrun ṣe ko oun yọ ninu akọlu naa, oun ṣaa kan ri i pe ibọn ko ba oun titi toun fi ba ẹsẹ oun sọrọ laarin wọn, toun si tọ ọna kan, bo tilẹ jẹ pe ẹru n ba oun pe ki ọna naa ma tun lọọ ja sọdọ awọn ajinigbe mi-in, tori awọn ẹgbẹ ajinigbe oriṣiiriṣii lo wa kaakiri igbo naa, ṣugbọn inu oun dun pe ọna naa jade siluu Galadimawa, loun ba wọkọ kọja si Kaduna lati fẹjọ sun.
Alaye tobinrin naa ṣe yii lo ran awọn ọlọpaa lọwọ ti wọn fi bẹrẹ si i finmu finlẹ, ọjọ keji lawọn ikọ ọlọpaa Operation Puff Adder (OPA) ati IRT fi pampẹ ofin gbe Haliru Abubakar, ọmọ bibi abule Magume, niluu Zaria, nipinlẹ Kaduna, ko si ka ju iwe mẹwaa lọ, o ni sabukeeti Wayẹẹki.
Nigba tọwọ ba a, o jẹwọ pe loootọ loun ji obinrin oniṣowo naa gbe, ati pe mọlẹbi lawọn, aburo baba oun ni iya rẹ, o darukọ awọn meji tawọn jọ ṣeto ijinigbe naa, Ọgbẹni Nuhu Ibrahim ati Rashidu Muntari, adugbo Tundungaudi, ni Zaria, lawọn naa n gbe, ati pe adehun tawọn jọ ṣe ni pe ki wọn ji obinrin naa gbe, ki wọn gbowo to towo lọwọ ẹ, ki wọn si pa a.
“Ọmọ aburo baba mi ni Binta loootọ, ṣugbọn a o jọ gbe ibi kan naa, ko si mọ pe emi ni mo ṣeto bi wọn ṣe ji oun gbe. Mo jẹ ẹ lowo, miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna irinwo naira (N1.4m) ni mo jẹ ẹ. Kẹkẹ Maruwa ni mo fi n ṣiṣẹ, oun lo ra awọn kẹkẹ kan fun mi pe ki n maa sanwo ẹ pada diẹdiẹ, miliọnu mẹta, ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un mẹsan-an (N3.9m), oṣu Disẹmba, ọdun 2020, lo yẹ ki n ti sanwo naa tan, ṣugbọn miliọnu meji aabọ ni mo ṣi san (N2.5m), lowo naa fi ku 1.4 miliọnu naira.
‘‘Nigba to n pe mi lori aago lemọlemọ pe owo oun da, mo ni ko tẹle mi lọ sọdọ ẹnikan temi naa fẹẹ gbowo lọwọ ẹ, ṣugbọn mo tan an jade ni, ọdọ awọn ajinigbe ti mo ti ba sọrọ tẹlẹ ni mo mu un lọ. Marun-un ni ikọ ajinigbe naa, meji ninu wọn ni mo mọ, wọn si ti sọ ibi ti ma a duro si tawọn ti maa ji wa gbe.
‘‘Gbara ti wọn jade si wa lojiji ni wọn ti ko wa wọ’gbo lọ. Mo sọ fun wọn pe ki wọn lọọ gbe ọkọ ayọkẹlẹ ti mo gun wa sẹgbẹẹ titi marosẹ kawọn eeyan le ro pe loootọ ni wọn ti ji wa gbe, ṣugbọn wọn o ṣe bẹẹ.
Adehun wa ni pe ki wọn gba miliọnu lọna ọgọrun-un (N100m) lọwọ ẹ tori mo mọ pe oniṣowo nla ni, owo wa lọwọ ẹ bii ṣẹkẹrẹ, lẹyin naa ni ki wọn pa a, ki wọn si pin temi fun mi lara owo naa.
‘‘Ọjọ marun-un la fi jọ wa lakata awọn ajinigbe ọhun, a ba awọn mi-in ti wọn ti ji gbe tẹlẹ nibẹ, ṣugbọn o ṣee ṣe foun lati raaye sa mọ wọn lọwọ tori wọn o so ṣẹkẹṣẹkẹ mọ ọn lọwọ bii tawa yooku. Nigba ti ẹnikan lara wọn tun waa mu emi naa kuro, to mu mi lọọ ba ẹgbẹ ajinigbe mi-in lo ṣẹṣẹ han si mi pe wọn ti ji emi gan-an alara gbe, tori mi o rẹni foju jọ ninu awọn yii. Ọkan lara wọn lo ni ki n pe ẹni to maa waa san owo itusilẹ fun mi. O to aadọta ikọ ajinigbe to wa kaakiri inu igbo naa.
‘‘Ọjọ ti wọn fẹẹ waa san owo itusilẹ mi ni mo raaye sa mọ wọn lọwọ, awọn ajinigbe naa ko si nitosi lọjọ yẹn, nibi ti mo ti n sa lọ, mo ja si oko kan, mo ri baba agbẹ kan, ni mo ba bẹ ẹ pe ko ya mi ni foonu ẹ, ni mo fi sọ fawọn eeyan mi pe ki wọn ma wulẹ lawọn n sanwo itusilẹ kankan o, mo ti raaye sa mọ wọn lọwọ.”
Bayii ni Abubakar n ka boroboro bii ajẹ tilẹ mọ ba, ṣugbọn Alukoro apapọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ti ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ rẹ, ati pe laipẹ, o maa too lọọ fimu kata ofin niwaju adajọ tawọn maa wọ ọ lọ.