Ọfiisi Ahamad Alawiye olorin Islam jona l’Ekoo

Kazeem Aderounmu

Guruguru ni ọfiisi gbajumọ olorin ẹsin Islam nni, Alhaji Ahamdu Alawiye, to wa ni Amori Shopping Complex, Ẹgbẹda jona patapata lasiko ti ina kan ṣadeede ṣẹ yọ lọfiisi ti wọn jọ wa loke kan naa.

Iyawo gbajumọ olorin Musulumi yii ti oun naa jẹ akọrin, Alhaja Rukaya Basirimi, ṣalaye fun akọroyin wa pe, “Idaji, ni nnkan bii aago marun-un aabọ ni ina yẹn ṣadeede sọ, bẹẹ lawọn eeyan ti wọn ri i ti n sare pe ileeṣẹ redio, ti wọn tun n pe awọn pannapanna. Alhaji ṣẹṣẹ ko awọn eeyan wa lọ si Umrah lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja ni. Ile gan-an ni mo wa ti awọn eeyan ti n fi fidio bi ọfiisi yẹn ṣe n jo ranṣẹ si mi. Ohun ti a gbọ ni pe studio kan to wa lẹgbẹẹ ọfiisi wa ni ina yẹn ti bẹrẹ. Wọn ni bi wọn ṣe muna de ni waya to wa ni studio ọhun gbina, bi ina ṣe bẹrẹ niyẹn, to si jo gbogbo oke kẹta ti ọfiisi tiwa naa wa nibẹ. Ọpọ dukia ati owo lo jona patapata.”

Obinrin olorin yii fi kun ọrọ ẹ pe abẹrẹ lo kere ju, awọn ko ri mu ninu ọfiisi ọhun,  gbogbo dukia ti awọn ko sibẹ pata lo jona patapata.

O ni, “Ọlọrun ko ni i ṣe nnkan ko ma fi aaye ọpẹ silẹ, a dupe pe gbogbo iwe irinna awọn eeyan, iyẹn pasipọọtu wọn, Ọlọrun ko jẹ ki o jona mọnu ọfiisi yẹn. Ohun  to si ṣẹlẹ ni pe Alhaji ki i ko awọn pasipọọtu sinu ọfiisi, emi ni wọn maa n ko wọn fun, ti wọn aa ni ki n lọọ tọju ẹ. Ohun ti Ọlọrun fi ṣaanu wa niyẹn.”

ALAROYE gbọ pe oke kẹta ti Ahmad Alawiye to ni ileeṣẹ Alhatyku Travels & Tours ni ọfiisi si, nikan lo jona pẹlu awọn ọfiisi bii mẹjọ mi-in, ati pe dukia aimọye miliọnu naira lo ba iṣẹlẹ buruku ọhun lọ.

Ahmadu Alawiye naa ba wa sọrọ lati Saudi, o ni, “A dupẹ fun Ọlọrun ti iṣẹlẹ buruku naa ko la ẹmi lọ, bo tilẹ jẹ pe a ko ri abẹrẹ mu jade, sibẹ mo fẹẹ fi da awọn eeyan wa loju pe awọn dukia wọn to wa nikaawọ wa, ko si ohunkohun to ṣe e.

Leave a Reply