Igbimọ tijọba gbe kalẹ lori awọn ọmọ-kewu ti wọn fiya jẹ ni Kwara ni ọna ti wọn gba lu wọn ko daa

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn igbimọ ẹlẹni mọkanla ti Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, gbe kalẹ pe gbe kalẹ lati ṣewadii lori fidio awọn ọmọ kewu ti wọn fiya jẹ nile kewu kan to wa ni agbegbe Ganmọ, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara ti jabọ iwadii wọn bayii fun gomina.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni alaga igbimọ oluwadii ọhun, Adajọ Idris Haroon, gbe abọ iwadii naa siwaju Gomina Abdulrazak, to si ni awọn gbọdọ yan awọn igbimọ ti yoo maa ri si ọrọ ile kewu lẹsẹkẹsẹ, o ni ohun ti awọn fẹ ki gomina ṣe ni pe ki o mu atunto ba ofin awọn ile kewu gbogbo, eyi ni yoo mu adinku ba ọpọ awọn iṣoro to n ba wọn finra lọwọ nipinlẹ Kwara.

 

Awọn igbimọ ọhun sọ pe ọna ti wọn gba lu awọn ọmọ ile kewu naa ko bojumu to, ti wọn si gbọdọ gbe igbeṣẹ lati ṣe atunṣe si ilana ti wọn yoo gba maa na awọn ọmọ naa. Adajọ Haroon sọ pe ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ni gomina ṣe ifilọlẹ awọn igbimọ ọhun ti awọn si ṣe ipade ni ẹẹmẹtala ọtọọtọ, awọn ṣe ni gbọngan apero to ileeṣẹ to n ri si ọrọ ohun amusagbara, bakan naa ni awọn tun ṣe ipade ni inu ọgba ile kewu ti wọn ti fiya jẹ awọn ọmọ naa, iyẹn Misbaudeen Arabic School, Ganmo, wọn ṣe ipade pẹlu awọn alaṣẹ ile kewu ati awọn obi ati alagbatọ awọn naa.

Gomina ti waa gboriyin fun awọn igbimọ naa fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe, to si ni awọn yoo farabalẹ wo gbogbo abọ iwadii ọhun finnifinni, ti yoo si gbe igbeṣẹ to ba kan, eyi ti yoo ṣe awujọ ati ile kewu ni anfaani. Gomina ni ọrọ iṣẹlẹ naa ye awọn daadaa, idi niyi ti awọn fi gbe awọn ọmọnran kalẹ ki wọn tun ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.

 

Leave a Reply