Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti sọ pe ko si ootọ ninu iroyin kan to n ja ran-in-ran-in latọdọ ijọba ana pe oun ti gba biliọnu marun-un Naira ninu asunwo ijọba.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin gomina, Ọlawale Rasheed, fi sita lo ti ran awọn araalu leti pe lasiko ibura fun gomina tuntun ni Adeleke ti kede titi ẹnu asunwọn owo ipinlẹ Ọṣun pa.
Ọlawale ni bawo ni gomina ti ko ti i ni anfaani si owo ijọba to fi ṣekede naa yoo ṣe le tọwọ bọ asunwọn ijọba lati ko iru owo bẹẹ?
O waa ke si awọn araalu lati ma ṣe feti si ahesọ awọn to ṣi n ka lara pe ijọba ti bọ lọwọ wọn, ati pe Gomina Adeleke wa lati sin awọn eeyan ni, ki i ṣe lati ṣe owo ilu baṣubaṣu.