Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọkunrin Hausa kan to jẹ Seriki awọn Hausa lagbegbe Kuntu, niluu Ilọrin, lagbọ pe o ti ku, ti eeyan mẹta mi-in si fara pa, nibi ijamba ọkọ ati Maruwa to waye lagbegbe Kuntu, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
ALAROYE gbọ pe nnkan bii aago mẹwaa aabọ aarọ ọjọ Aje, ni ijamba ọhun waye latari pe ijanu ọkọ to n ko omi inu ọra ati awọn omi inu ike kan ja, to si bẹrẹ si i kọ lu awọn eeyan, o gba kẹkẹ Maruwa kan sinu odo, eeyan mẹta ninu marun-un to wa ninu Maruwa naa fara pa kọja afẹnusọ, bakan naa lọkọ ọhun ko tun duro, o lọọ ṣe akọlu si Mallam kan ti wọn pe ni seriki awọn Hausa to wa ni agbegbe Kuntu, niluu Ilọrin.
Ileewosan aladaani kan ni wọn ko gbogbo wọn lọ ni agbegbe naa, sugbọn ileewosan mẹta ọtọọtọ ni wọn gbe seriki lọ ki wọn too gba a, bo tilẹ jẹ pe ko lo wakati meji ni ileewosan ọhun to fi ku.
Wọn ni dẹrẹba to wa ọkọ ọhun fori gba gilaasi ọkọ, ori ẹ bẹ, sugbọn o sa lọ. Titi di akoko ta a n ko iroyin yii jọ, wọn o ti i mọ ibi ti dẹrẹba naa wa, awọn ọlọpaa agọ Adewọle si ti gbe ọkọ ati Maruwa tawọn eeyan ti ni ijamba naa lọ si agọ wọn lẹyin ti wọn yọ Maruwa kuro ninu odo tan.