O ma se o, awọn ọmọde mẹrin gan mọ ina n’Ilẹ-Oluji

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ọmọ keekeekee mẹrin ni wọn pade iku ojiji, ti ori si ko awọn meji yọ lẹyin ti waya ina ja le wọn lori ninu ṣọọbu ti wọn wa lagbegbe kan ti wọn n pe ni Oke-Agọ, n’Ilẹ-Oluji, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja.
Awọn ọmọde mẹfẹẹfa la gbọ pe wọn ko ara wọn jọ sinu ṣọọbu obinrin kan ti wọn fi kọntena ṣe nigba ti waya ina ti wọn ṣẹṣẹ n so si agbegbe naa deede ja lojiji, eyi to ṣeku pa mẹrin ninu wọn loju-ẹsẹ, tawọn meji yooku si dero ọsibitu.
Eyi ni alaye ti ọkan ninu awọn ọmọ ti ori ko yọ ninu ijamba ọhun, Blessing ṣe fawọn oniroyin to ṣe abẹwo si i nile-iwosan to ti n gba itọju.
‘‘Ṣe la ri i tawọn Nẹpa muna wa lojiji ninu ṣọọbu ta a ti n ṣere, idunnu ati ayọ ni gbogbo wa fi pariwo ọp NEPA, a o ti i pari eyi ta a fi n gbọ iro bi awọn waya ina ṣe n dun parapara loke ṣọọbu ta a wa, pẹlu ibẹru ni gbogbo wa fi sa jade laimọ pe wayA ina ọhun ti ja sori kọntena ta a wa ninu rẹ.
Ohun ta a ṣakiyesi ni pe ina ti mu ki ẹsẹ wa gan mọlẹ, ti a ko si le sa lọ mọ, mo saa wa gbogbo ọna jokoo sori pako kan to wa ninu ṣọọbu wa, nigba ti mo boju-wẹyin ni mo ri i pe awọn ọrẹ mi n gbọn pẹpẹ, ti gbogbo wọn si n pọ ẹjẹ lẹnu.
Emi nikan ni mo n pariwo titi tawọn eeyan fi waa gbe wa lọ si ọsibitu ijọba to wa ni Ilẹ-Oluji.’’
Obinrin to ni ṣọọbu ọhun, Abilekọ Ronkẹ Adebiyi, ṣalaye pe oun ko si nitosi lasiko ti iṣẹlẹ naa waye.

O ni ibi kan loun wa lalẹ ọjọ naa ti ẹnikan fi pe oun pe ṣọọbu oun ti n jona, leyii to mu koun tete mori le ọna ibẹ nitori awọn ọmọ ti oun fi silẹ.
O ni Blessing nikan loun ri to jade nigba toun de iwaju ṣọọbu, tawọn yooku ko le dide mọ nibi ti wọn sun silẹ si.
Loju-ẹsẹ lo ni awọn ti ko gbogbo wọn lọ si ileewosan.

Adebiyi ni oun gbagbọ pe airi afẹfẹ ọsigin lo fawọn ọmọ naa lasiko lo jẹ ki awọn mẹrin tete ku ninu wọn, ti ẹni karun-un si wa lẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun, ko le rin, bẹẹ ni ko le sọrọ.
Lati ibẹ lo ni awọn ti ko awọn meji yooku lọ si ọsibitu pajawiri to wa niluu Ondo, o ni ko pẹ rara ti wọn fi yọnda ọkan ninu awọn ọmọ naa lẹyin to gba itọju tan, nigba ti wọn ni ki awọn maa gbe ẹni keji rẹ lọ si ileewosan ẹkọṣẹ iṣegun Fasiti Ọbáfẹ́mi Awolọwọ, to wa n’Ile-Ifẹ.

Abilekọ Adebiyi ni ọmọ ẹgbọn oun ni meji ninu awọn ọmọ to fara gba ninu iṣẹlẹ ọhun, ọlude Ajinde ni wọn waa lo lọdọ oun ki ajalu buruku naa too sẹlẹ.
A gbọ pe aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ẹkun Guusu ipinlẹ Ondo nileegbimọ aṣofin agba, Ọnarebu Nicholas Tofowomọ, ti dide sọrọ awọn ọmọ naa.
Sẹnetọ ọhun fi obi awọn ọmọ ọhun lọkan balẹ pe oun ṣetan lati gbena woju awọn to n pin ina ọba lẹkun Benin (Benin Electricity Distribution Company, BEDC) lori iṣẹlẹ naa.
Bakan naa ni aṣofin ọhun tun rọ awọn eeyan lati jawọ ninu kikọ ile tabi ṣọọbu si abẹ waya ina nitori ewu nla to rọ mọ ọn.

Leave a Reply