Ẹni kan ku lojiji, ọpọ eeyan fara gbọta ‘Ikarẹ Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹni kan pade iku ojiji nigba tọpọ awọn eeyan mi-in tun fara gbọta lasiko rogbodiyan nla kan to waye niluu Ikarẹ Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko, nitori ọrọ oye.

Alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni wahala ọhun bẹrẹ wẹrẹ pẹlu bi igun mejeeji tí wọn n du oye Olokoja tilu Ikarẹ ṣe doju ija kọ ara wọn.

Bi ilẹ ọjọ Isẹgun, Tusidee, tun ṣe n mọ ni iro ibọn tun ti bẹrẹ si i dun lakọlakọ kaakiri ilu, iwaju aafin Olukarẹ to wa nitosi ọja ọba lawọn ọmọ ẹgbẹ igun kan duro si, bẹẹ lawọn igun kejì naa tẹ ẹ pa si iyana adugbo kan ti wọn n pe ni Ọlọkọ, lati ibẹ lawọn igun mejeeji to n binu ti yinbọn funra wọn.

Ki i ṣe ẹru diẹ ni rogbodiyan ọhun da sọkan awọn araalu pẹlu bawọn arinrin-ajo atawọn ọlọja ṣe sa pada sile, ti gbogbo igboro ilu sì da paroparo bii ọja ijẹta.

O to bii wakati meji ti gbogbo nnkan ti daru kawọn ẹsọ alaabo to wa niluu Ikarẹ ati agbegbe rẹ too ba wọn da si i, awọn soja atawọn ọlọpaa ni wọn pada pana gbogbo rogbodiyan naa ko too dohun tapa ko ni i ká mọ.

Awọn ẹsọ alaabo ọhun ni wọn ṣeto bí wọn ṣe ko awọn to fara pa lọ sile-iwosan ijọba to wa n’Ikarẹ, nibi ti ọpọ wọn ti n gba itọju lọwọ.

 

 

 

 

Leave a Reply