Faith Adebọla, Eko
Ori gige ika abamọ jẹ lọwọ lawọn gende mẹta yii wa lọwọlọwọ yii, tori akolo ọlọpaa ni wọn bọ si nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹrin yii, nigba tọwọ palaba wọn segi nidii iwa pamọlẹkun jaye ti wọn n hu.
Orukọ awọn mẹtẹẹta ni Goddey Omuyibo, ẹni ọdun mejilelọgbọn, ti wọn n pe ni Aro Ghetto Boy, Destiny Nwanga, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ti inagijẹ rẹ n jẹ Aro Smiling God. Aro Do or Die ni wọn n pe ẹni kẹta wọn, ẹni ọdun mẹtalelogun pere ni, Ebuka Igwe ni orukọ ẹ gan-an.
Gẹgẹ bi atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, SP Benjamin Hundeyin, fi ṣọwọ s’ALAROYE l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, ṣe wi, ibudokọ Toyota, to wa nitosi Oṣodi, nipinlẹ Eko, lọwọ ti ba awọn mẹtẹẹta, ibọn oyinbo ti wọn n pe ni Beretta kan ni wọn ka mọ wọn lọwọ, pẹlu katiriiji ọta ibọn mẹrin ti wọn o ti i yin.
Wọn ni Goddey sọ fawọn ọlọpaa lẹyin tọwọ ba wọn pe iṣẹ adigunjale lawọn n ṣe, ṣugbọn ẹni meji pere lawọn ṣi ja lole tọwọ fi ba awọn.
Nigba tawọn ọlọpaa n ṣewadii, wọn jẹwọ pe Ojule keje, Opopona Alaaji Mọnsuru, ni Ijegun, lawọn ti n ṣepade, ibẹ si lawọn ti n pin owo atawọn dukia tawọn ba ji gbe, wọn ni ibẹ lojuko awọn.
Iwadii tun fihan pe Nwanga maa n ṣiṣe titun pọmpu ọkọ ṣe ni ọja paati mọto to wa ni Ladipọ, Omuyibo naa si maa n pe ara ẹ ni ajorin-mọrin wẹda (welder), ṣugbọn gbogbo wọn n fi iṣẹ wọnyẹn ṣe bojuboju lasan ni, ogbologboo adigunjale ni wọn.
Wọn ni Omuyibo tun jẹwọ pe oun maa n ta oogun oloro, oun si maa n ra a.
Ṣa, iwadii ṣi n tẹsiwaju lori wọn, ikawọ awọn ọtẹlẹmuyẹ lawọn mẹtẹẹta wa bayii gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, CP Abiọdun Alabi, ṣe paṣẹ.
Ibẹ ni wọn maa gba dele-ẹjọ.