Ọmọbinrin yii maa n dibọn bii ẹni to fẹẹ ran awọn ti ko mọ kaadi ATM i lo lọwọ, ni yoo ba paarọ ẹ mọ wọn lọwọ

Faith Adebọla

Oriṣiiriṣii kaadi ATM ti wọn fi n gbowo lẹnu ẹrọ mẹtadinlogun ni wọn ba lọwọ ọmọbinrin ẹni ọdun mẹrinlelogun (24) ti wọn porukọ ẹ ni Juliet Chinozom Osasi yii, ko si tiẹ ninu gbogbo kaadi naa, awọn kaadi to fọgbọn paarọ mọ awọn onikaadi lọwọ ni, ti yoo fi le wọ owo wọn jade ti wọn ba ti lọ tan.
Ba a ṣe gbọ, niṣe ni Juliet to n gbe ọna Enugu, lagbegbe Sabon Gari, ni Kano, maa n lugọ kaakiri awọn ibi ti ẹrọ ATM wa nipinlẹ Kano, to ba ti ri ẹni to fẹẹ gbowo, paapaa tẹni naa ko ba mọ kaadi ATM i lo daadaa, yoo sun mọ wọn lati ran wọn lọwọ, o maa n sọ fun wọn pe oṣiṣẹ banki loun, iṣẹ riran awọn to fẹẹ lo ATM ni wọn yan foun, yoo si ba wọn gbowo jade.
Ṣugbọn nigba to ba fẹẹ da kaadi pada fun onikaadi, niṣe lafurasi ọdaran yii maa dọgbọn paarọ kaadi naa pẹlu kaadi mi-in to jẹ ti banki tẹni naa n lo. Lọpọ igba lawọn onikaadi yii ki i mọ pe Juliet ti paarọ kaadi mọ wọn lọwọ.
Ti onikaadi ba ti lọ tan, wọn ni Juliet maa lọ sidii ẹrọ ATM mi-in to jinna saduugbo naa, yoo si wọ owo onitọhun jade ninu akanti rẹ, yoo fere ge e.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano, SP Abdullahi Haruna Kiyawa, to sọrọ yii di mimọ sọ pe ẹnikan ọmọbinrin naa ṣẹṣẹ lu ni jibiti bẹẹ lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta to kọja, Ọgbẹni Yusuf Tijani, lo waa fẹjọ sun ni ẹka ọlọpaa Nasarawa, lawọn ọtẹlẹmuyẹ ba bẹrẹ si i tọpinpin ẹ, kọwọ too ba a lọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin yii, lọna marosẹ Muritala Mohammed, nipinlẹ Kano.
Wọn lafurasi ọdaran yii ti jẹwọ pe loootọ loun fi jibiti wọ ẹgbẹrun mẹẹẹdogun Naira (N15,000) jade ninu akaunti rẹ, ootọ loun si ti ṣe bẹẹ fọpọ eeyan.
Iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ yii. Kọmiṣanna ọlọpaa wọn, CP Sumaila Shua’ibu Dikko, ti lawọn maa foju ẹ bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply