Ẹni ti Buahri ba fọwọ si lati dupo alaga la maa ṣatilẹyin fun-Awọn gomina APC

Jọkẹ Amọri

Ẹgbẹ awọn gomina to jẹ ti ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti fi ipinnu wọn han pe ẹnikẹni ti Buhari ba fọwọ si lati du ipo alaga lawọn maa ṣe atilẹyin fun lasiko idibo gbogbogboo wọn ti yoo waye ni Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu yii.

Wọn fi ọrọ yii lede lẹyin ipade ti wọn ṣe pẹlu Aarẹ Buhari ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Alaga igbimọ alamoojuto ẹgbẹ naa to tun jẹ Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni, lo ko awọn gomina ẹgbẹ rẹ sodi lọ sọdọ Aarẹ Buhari lati ṣe ipade naa.

Gomina ipinlẹ Kebbi, Atiku Bagudu, to jẹ alaga awọn gomina ọhun sọ pe awọn ṣetan lati ṣe atilẹyin fun gbogbo igbesẹ ti yoo ba yọri si fifa oludije kan kalẹ lọjọ idibo naa. Nigba to n sọrọ lori awọn ti wọn n fapa janu, ti wọn si n sọ pe dandan ni ki eto idibo waye, Bagudu ni ẹgbẹ to fara mọ ilana ijọba awa-ara-wa ni ẹgbẹ awọn, eyi ti yoo mu ki awọn fara mọ fifa ẹni kan ṣoṣo kalẹ, ki awọn to ku si gbaruku ti i. Bẹẹ lo gba awọn yooku niyanju lati jẹ ki awọn tẹle ifẹ inu ẹgbẹ awọn, nitori  igbimọ apaṣẹ to ga ju lọ ti pin ipo naa, iyẹn awọn ọmọ igbimọ to n paṣẹ ẹgbẹ naa bayii.

O fi kun un pe awọn ti wọn ba taku lori ipinnu yii naa, ko si ohun ti awọn yoo ṣe fun wọn bi igbesẹ ti wọn ba fẹẹ gbe ba ti wa ni ibamu pẹlu ilana ẹgbẹ, nitori awọn ko ni i fẹẹ ta ko ominira awa-ara-wa.

Gomina yii ni gbogbo awọn lawọn mọ pe ohun to maa dun ninu Aarẹ ni pe ki awọn fa ọmọ oye kan ṣoṣo kalẹ, nitori o wa ni ibamu pẹlu ofin dẹmokiresi, niwọn igba ti asọyepọ ba si ti wa, to si jẹ pe oko kan naa lawọn jọ n ro gẹgẹ bii ẹgbẹ, o ni ko ni i si iyọnu.

Nigba to n sọrọ lori boya awọn kan le kọti ikun, ki wọn si fa joka tuntun yọ lasiko idibo naa, o ni ko si ohun to jọ bẹẹ nitori ẹyin Aarẹ Buhari ni gbogbo awọn wa, ohun to si fẹ naa ni awọn yoo ṣe.

‘‘A dupẹ lọwọ Aaarẹ, a si dupẹ lọwọ igbimọ afun-n-ṣọ fun gbogbo ohun ti wọn n ṣe.

Tẹ o ba gbagbe, ki Aarẹ Buhari to tẹkọ leti lọ si London fun itọju ara rẹ ni wọn ti n sọ pe o ti fọwọ si awọn kan fun diẹ ninu awọn ipo ti wọn fẹẹ tori ẹ dibo ni Satide. Lara rẹ ni ti ipo alaga, eyi to ṣe pataki ju lọ nitori oun ni yoo maa dari awọn ti yoo tukọ ẹgbẹ.

Gomina ipinlẹ Nasarawa tẹlẹ, Adamu, ni wọn pe ni aayo Buhari fun ipo naa.

Lara awọn to wa nibi ipade naa ni Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, awọn gomina ipinlẹ ti APC n dari mẹrẹẹrindinlogun

Leave a Reply