Ẹni to ba fẹẹ fiku ṣere nikan lo maa sọ pe ko sohun to n jẹ Korona – Sanwo-Olu

Faith Adebọla, Eko

 Ikilọ ti lọ sọdọ awọn olugbe ipinlẹ Eko latọdọ Gomina Babajide Sanwo-Olu nipa arun Koronafairọọsi pe ki wọn ma fi arun naa ṣere rara, pẹlu bawọn kan ṣe n sọ pe arumọjẹ ni. Sanwo-Olu ni afi ẹni to ba fẹẹ fiku ṣere nikan lo maa sọ pe ko sohun to n jẹ Korona, o ni arun naa wa gidi, ki i ṣe arumọjẹ rara.

Ọjọ Aiku, Sannde yii, ni Babajide ke tantan bẹẹ nigba to n sọrọ nipa ibi ti nnkan de duro lori iṣapa ijọba rẹ lati dena itankalẹ arun aṣekupani naa, o ni iyalẹnu lo jẹ foun lati maa gbọ pe awọn kan n sọ pe ko sohun to n jẹ Koro, arun arumọjẹ lasan ni, Sanwo-Olu ni ko sohun to yara paayan bii aimọkan ati afojudi.

O bẹ awọn olugbe Eko lati ma ṣe gba ahesọ yii gbọ, tori arun to n ṣọṣẹ gidi ni Korona, ohun to si yẹ ni lati sa fun un, lati pa awọn eewọ ẹ ati alakalẹ ijọba lori ẹ mọ. Gomina ni o san keeyan ma lugbadi arun ọhun ju keeyan fara kaaṣa tan ko too gbagbọ pe o wa lọ.

Amọ ṣa o, gomina ni yatọ si bi awọn to n lugbadi Koro ẹlẹẹkeji ṣe n pọ si i, awọn ni iroyin ayọ fawọn ti wọn n gba itọju nileewọsan ti wọn ti n bojuto arun yii, o lawọn ti ṣe idasilẹ ileeṣẹ afẹfẹ ti wọn n fẹ simu, (oxygen) to maa pese ọọdunrun (300) afẹfẹ ọsijin loojọ, fawọn ti ti wọn nilo itọju pajawiri, lati doola ẹmi wọn. O lawọn ṣi maa kọ iru ileeṣẹ bẹẹ si i laipẹ.

Ṣaaju ni Igbakeji gomina Eko naa, Ọbafẹmi Hamzat, ti ṣekilọ pe arun Korona to tun n gberi bayii ko mọ ọjọ-ori tabi ipo rara, tọmọde tagba lo wa ninu ewu ẹ. Ninu ọrọ rẹ ọhun lo ti fẹnu ara rẹ kede pe arun Korona lo pa aburo oun, Dokita Haroun Hamzat, to doloogbe lọsẹ to kọja yii.

O ni ko ti i sọna abayọ lori arun yii ju keeyan maa kiyesara, ko si pa awọn ofin to rọ mọ ọn mọ, tori oju lalakan fi n sọri lọrọ ọhun gba bayii.

Leave a Reply