Ẹni to ba yin banga lasiko ọdun to n bọ yii l’Ekoo maa rẹwọn he – Ijọba

Faith Adebọla, Eko

Ikilọ ti lọ sọdọ awọn obi atawọn ọdọ lati ọdọ ijọba ipinlẹ Eko pe ko gbọdọ si ohunkohun to jọ yinyin banga, iṣana ọdun atawọn nnkan iṣere to n dun bii ibọn lasiko pọpọṣinṣin ọdun Keresi ati ọdun tuntun to wọle de tan yii, aijẹ bẹẹ, ki ẹni ti wọn ba gba mu ṣetan lati fẹwọn jura ni.

Oludamọran pataki fun gomina ipinlẹ Eko lori ọrọ sisọ Eko dilu aje nla ti wọn n pe ni (Central Business District), Ọgbẹni Gbenga Oyerinde, lo sọrọ naa ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Ẹti, Furaidee yii.

Gbenga ni ofin to de yinyin awọn nnkan alariwo bii banga lasiko ọdun ko ṣẹṣẹ bẹrẹ nipinlẹ Eko, ijọba ko si ti i figba kan wọgi le e, ṣugbọn lọtẹ yii, awọn ṣetan lati wọ ẹnikẹni to ba ṣẹ sofin ọhun dele-ẹjọ, lati fimu kata ofin.

O ni nnkan o fara rọ lasiko yii rara, eto aabo ti ni ipenija, tori naa, ko ni i b’ọgbọn mu fẹnikẹni lati tun maa ṣẹru ba awọn ọlọja ati olugbe pẹlu iro to jọ ti ibọn, ti banga yinyin maa n mu wa. Yatọ siyẹn, awọn janduku ati adigunjale le fi iro banga kẹwọ, ki wọn si maa yinbọn gidi lati ṣe awọn araalu ni ṣuta.

O ni ijọba ti fun awọn agbofinro laṣẹ lati fi pampẹ ofin gbe ẹnikẹni, ibaa jẹ ọmọde tabi agba, to ba ṣe ohun to lodi sofin yii.

Oyerinde waa rọ awọn olugbe ilu Eko lati ṣakiyesi ohunkohun to le ṣokunfa ijamba ina lasiko ọdun, ki awọn obi si so ewe agbejẹẹ mọ awọn ọmọ wọn lọwọ, ki kaluku le fi irọrun ṣajọyọ ọdun to wọle de tan ọhun.

 

Leave a Reply